Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Iyalẹnu gbaa ni ọrọ baale ile kan torukọ ẹ n jẹ Eluyẹra Wasiu, ẹni ọdun marundinlogoji (35) to fun iyawo ẹ loyun, to si tun ran agbanipa si i pe ko lọọ pa obinrin naa toyun-toyun, l’Ogijo, nipinlẹ Ogun.
Aarọ ọjọ Aje, Mọnde, ti i ṣe ọjọ kẹta, oṣu kin-in-ni, ọdun tuntun yii, ni Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, fi iṣẹlẹ yii sita, ninu eyi to ti ṣalaye pe awọn ọmọ Naijiria rere ni wọn ri Wasiu ati ẹnikeji ẹ, Adeniyi Samuel, to ran niṣẹ iku siyawo ẹ, nibi ti wọn ti n ja gidigbo laduugbo Oponuwa, l’Ogijo, ti wọn sare pe teṣan ọlọpaa. Ti wọn sọ fun wọn pe awọn meji naa fẹẹ lu ara wọn pa o, eyi si jẹ ọjọ ọdun tuntun ti i ṣe ọjọ kin-in-ni, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022. Bawọn ọlọpaa ṣe lọ sibẹ lati mu awọn to n ja naa niyẹn, ki wọn ma baa para wọn.
Nigba ti wọn mu wọn ni idi ti wọn fi n ja di mimọ fawọn ọlọpaa. Samuel ti Wasiu bẹ niṣẹ lo kọkọ rojọ.
Ọkunrin ẹni ọdun mọkandinlọgbọn(29) naa ṣalaye pe Wasiu ni koun ba oun pa iyawo oun, Bọla Taiwo, to wa ninu oyun. O ni ẹgbẹrun mẹwaa naira ni Wasiu sọ pe oun yoo san fun iṣẹ ipaniyan naa, oun si gba lati ba a ṣe e, o si foun lẹgbẹrun marun-un naira gẹgẹ bii asansilẹ, o ni toun ba pari iṣẹ ipaniyan naa, oun yoo san eyi to ku.
Ai ti i ṣiṣẹ ọhun lo ni o fa a to fi wa n ba oun ja nigboro, to fẹẹ gba ẹgbẹrun marun-un to kọkọ san.
Iwadii awọn ọlọpaa fidi ẹ mulẹ, pe tọkọ-tiyawo ni Wasiu Eluyẹra ati Bọla Taiwo to fẹẹ pa yii tẹlẹ. Ija lo de laarin wọn to fi di pe kaluku gba ọna ọtọọtọ, ti wọn ko fẹra wọn mọ. Lẹyin igba naa ni Wasiu fẹ iyawo mi-in toun ati ẹ jọ n gbe bayii.
Ṣugbọn bo ṣe jẹ pe ija tọkọ-tiyawo ko ṣee da si i, to jẹ wọn tun le pari ẹ bo ti wu ko pẹ to, niṣe ni Wasiu ati Bọla tun pari ija wọn, ni wọn ba tun n fẹra wọn pada, nibẹ loyun ti de lojiji, ti Bọla loyun fọkọ to ti kọ silẹ tẹlẹ.
Oyun ti Bọla ni yii ko dun mọ Wasiu, nitori ko fẹ kiyawo tuntun to wa nile binu to ba gbọ, iyẹn lo fi ni ki Bọla jẹ kawọn ṣẹ oyun naa, iyẹn si loun ko ni i ṣẹyun, ọmọ loun yoo fi ọlẹ ayọ to sọ ninu oun naa bi.
Latigba ti Bọla ti loun ko ni i ṣẹyun ni Wasiu ti n wa ọna ti yoo fi pa a ti ọrọ oyun naa yoo pari sibẹ. Ẹẹmeji ọtọọtọ lo ra ounjẹ lọ fun obinrin oloyun naa to si ti fi majele si i, ṣugbọn ọla inu kan ati bi Ẹlẹdaa rẹ ṣe wa lẹyin rẹ, Bọla ko jẹ ounjẹ ọhun, ọkọ to fẹẹ pa a ko si ri i pa.
Nigba ti gbogbo igbiyanju lati pa a yii ko bọ si i lo lọọ ba Samuel Adeniyi pe ko ba oun pa a. Wasiu funra ẹ jẹwọ fawọn ọlọpaa, pe oun loun bẹ Samuel lọwẹ pe ko ba oun pa Bọla Taiwo, oun tun funra oun mu un lọ sile obinrin naa ko le da a mọ to ba fẹẹ pa a, oun si tun fun un ni fọto rẹ pẹlu.
Lẹyin naa loun fun un lẹgbẹrun marun-an Naira asansilẹ, pe to ba pari iṣẹ, oun yoo san ẹgbẹrun marun-un to ku fun un. O ni Samuel waa kọ, ko ba oun pa a, o waa n yan fanda kiri lọjọ ọdun tuntun, o ni ohun to fa ija awọn niyẹn tawọn araadugbo fi pe ọlọpaa.
CP Lanre Bankọle ti i ṣẹ ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti ni ki iwadii to lagbara tẹsiwaju lori iṣẹlẹ yii, ki wọn si gbe awọn mejeeji naa lọ si kootu fun igbẹjọ.