Faith Adebọla
Pẹlu bi ayẹyẹ ọdun itunu aawẹ ṣe gbode kan lasiko yii, Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka ni ni toun, ko sohun ti yoo dun mọ oun ju ki oun lọọ tunu aawẹ pẹlu gbajugbaju ajijagbara ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ, tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho lọ. Idi eyi lo si ṣe ṣabẹwo si ọkunrin naa lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kin-in-ni, oṣu Karun-un yii, lorileede olominira Bẹnẹ.
Ẹnubode ilẹ wa to wa ni bọda Sẹmẹ, ni ilu-mọ-ọn-ka akọwe-kọwura nni, Ṣoyinka, gba sọda si ilu Kutọnu, lorileede Benin ọhun.
Nigba tawọn aṣọbode n yẹ iwe irinna rẹ wo lẹnuboode, niṣe lawọn ero rẹpẹtẹ ti wọn foju gan-an-ni baba agbalagba naa ya bo o, ti wọn si da ọpọ ibeere bolẹ, wọn fẹẹ mọ ibi ti Ṣoyinka n lọ ati ohun to fẹẹ lọọ ṣe.
Ṣoyinka fesi pe ọdọ Sunday Igboho loun n lọ, ati pe oun fẹẹ lọọ ṣinu pẹlu rẹ nibi to wa ni, tori aawẹ ti fẹẹ pari.
Ọrọ yii pa awọn eeyan lẹrin-in, wọn si ran an leti pe atoun ati Sunday Igboho ki i ṣe ẹlẹsin Musulumi, wọn o ki i ṣe alaawẹ, bawo ni ti ọrọ iṣinu ṣe waa jẹ, ṣugbọn Ṣoyinka fesi, o ni ko pọn dandan, ko si sohun to buru nibẹ. O lo wu oun lati ri Sunday Igboho, koun si ṣe koriya fun un tori ipo ti ko barade to n la kọja.
“Asiko aawẹ Ramadan dara lati fun ọmọlakeji ẹni niṣiiri, ka si ṣe koriya fun ara wa, bẹẹ lo si ri lawọn asiko ọdun mi-in,” gẹgẹ bo ṣe wi.
A gbọ pe nigba ti Ṣoyinka de ọdọ Sunday Igboho, oun ati Olori ẹgbẹ ajijangbara nni, Ọjọgbọn Banji Akintoye, lo gba a lalejo, wọn si dupẹ lọwọ ọkunrin naa fun ẹmi rere to ni, ati bo ṣe fi ẹmi ibanikẹdun han, to si fun Sunday Igboho niṣiiri.
Tẹ o ba gbagbe, ninu oṣu Kẹjọ, ọdun to kọja, ni Ọjọgbọn Ṣoyinka ti ke si ijọba orileede Bẹnẹ lati tu Sunday Igboho silẹ lahaamọ, o ni ki wọn jẹ ko maa rin irinajo rẹ lọ, tori ko dẹṣẹ kankan ni Naijiria, ti wọn yoo fi tori rẹ sọ ọ sahaamọ.
Ọjọ kọkandinlogun, oṣu Keje, ọdun 2021, lawọn alaṣẹ orileede naa mu Sunday Igboho ati iyawo rẹ, Rọpo Adeyẹmọ, sahaamọ lasiko ti wọn fẹẹ wọ baaluu lọ sorileede Germany. Ọjọ kẹta ni wọn tu iyawo rẹ silẹ, ṣugbọn wọn gbe Sunday Igboho lọọ ile-ẹjọ, bo tilẹ jẹ pe ẹjọ naa ko tẹsiwaju mọ.
Inu oṣu kẹta ọdun yii ni wọn da a silẹ lahaamọ, ṣugbọn wọn ṣi fofin de e lati ma ṣe kuro ni orileede naa, ko si gbọdọ kopa ninu ijijangbara kankan.
Latigba ti wọn ti mu Sunday Igboho ni Baba Akintoye ti wa lọdọ rẹ ni Kutọnu, ti wọn si n ṣeranlọwọ to yẹ lati da a silẹ.