Jide Alabi
Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii ni pasitọ ijọ Sẹlẹ, Wolii Israel Ọladele, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Dele Genesis, ti ọgba ẹwọn de lẹyin ti wọn ran an lẹwọn lori ẹsun pe o lu jibiti owo to to miliọnu mọkanla naira.
Ogunjọ, oṣu kọkanla, ọdun to kọja, ni wọn sọ ọkunrin ojiṣẹ Ọlọrun ijọ Sẹlẹ Global Genesis Parish, Israel Ọladele Ogundipẹ, sẹwọn ọdun meji. Obinrin oniṣowo kan to n gbe niluu oyinbo, Arabinrin Ọlaide Williams-Oni, lo gbe e lọ sile-ẹjọ. Ẹsun to si fi kan an ni pe o fọgbọn gba miliọnu mọkanla lọwọ oun.
Nigba ti ọrọ ọhun dele-ẹjọ, koko ẹsun meje ni wọn ka si Wolii yii lẹsẹ, iyẹn lọdun 2011, ki wọn too sọ ọ sẹwọn ninu oṣu kọkanla, ọdun to kọja.
Titi di asiko yii ni Wolii ijọ Sẹlẹ yii ko ti i ba oniroyin sọrọ, awọn amugbalẹgbẹẹ sọ pe yoo ṣe bẹẹ lẹyin isinimi ranpẹ to n ni lọwọ.