Wọn ṣi n wa awọn agbẹ mẹrin tawọn agbebọn ji gbe n’Ifọn

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Titi di ba a ṣe n sọ yii ni wọn ṣi n wa awọn agbẹ mẹrin ti wọn ji gbe lagbegbe Ifọn, nijọba ibilẹ Ọsẹ, laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja.

Awọn agbẹ ọhun, ọkunrin mẹta ati obinrin kan, la gbọ pe wọn jẹ ọmọ bibi ilẹ Akoko, ṣugbọn ti wọn n ṣiṣẹ agbẹ lagbegbe ijọba ibilẹ Ọsẹ.
Inu oko naa ni wọn n lọ laaarọ ọjọ ọhun tawọn agbebọn fi da wọn lọna nitosi Ẹlẹgbẹka, ti wọn si fipa ko gbogbo wọn wọnu igbo lọ.
Awọn ajinigbe naa ti kan si ẹbi awọn agbẹ yii, ti wọn si ni ki wọn waa san miliọnu mẹrindinlogun Naira gẹgẹ bii owo itusilẹ, leyii to tumọ si pe, miliọnu mẹrin Naira ni wọn fẹẹ gba lori ọkọọkan awọn ti wọn ji gbe yii.

Ọdẹ ibilẹ atawọn fijilante agbegbe Ọsẹ, pẹlu iranlọwọ awọn ẹgbẹ wọn lati awọn ilu bii Idoani, Ipesi ati Ifira Akoko la gbọ pe wọn ti fọn ara wọn sinu awọn aginju to wa laarin aala ipinlẹ Ondo, Edo ati Kogi, lati ṣawari awọn ti wọn ji gbe ọhun, ṣugbọn gbogbo akitiyan wọn ko ti i so eeso rere titi di ba a ṣe n sọrọ yii.
Nigba ta a kan si Funmilayọ Ọdunlami to jẹ Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo lati fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni ko ti i sẹni to fọrọ ijinigbe tuntun naa to awọn leti.

Leave a Reply