Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Titi di ba a ṣe n sọ yii ni wọn ṣi n wa ọga awọn dokita ile-iwosan ijọba to wa n’Idoani, Dokita Olufẹmi Adeogun, atawọn meji mi-in ti wọn ji gbe lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ ta a wa yii.
Awọn ajinigbe naa la gbọ pe wọn da ọkọ tawọn eeyan ọhun wa ninu rẹ duro lasiko ti wọn de ibi ti ọna ti bajẹ lagbegbe Iwani/Idoani, ti wọn si fipa ji awọn mẹtẹẹta gbe sa lọ.
Ori lo ko awakọ to gbe awọn oṣiṣẹ yii lọjọ naa pẹlu bawọn oniṣẹẹbi ọhun ṣe yinbọn lu u nibi to ti n gbiyanju ati sa mọ wọn lọwọ.
Ọkunrin yii ṣi wa nileewosan kan to ti n gba itọju ni gbogbo asiko ta a fi n kọ iroyin yii lọwọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro, ni igbesẹ ti bẹrẹ lori bi awọn ti wọn ji gbe ọhun yoo ṣe di riri pada laipẹ rara.