Wọn ba oku Funkẹ, kooṣi ere idaraya ipa jija, nileetura kan n’llọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọ Abamẹta, Satide, ọṣẹ yii, ni wọn ba oku Olufunke Ogunsuyi to jẹ olukọni ere idaraya ipa jija (kickboxing) nipinlẹ Ogun, to si waa kopa nibi idije ere ọhun to n lọ lọwọ ni papa isere ilu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ni yara ileetura to de si ni wọn ti ba oku rẹ.

Aago mejila ọṣan, ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, ni wọn n reti ki Olufunkẹ, o waa dari asekagba ere idaraya ọhun ni Papa isere ilu Ilọrin, ṣugbọn wọn reti arabinrin naa wọn ko ri i, wọn pe ẹrọ ibanisọrọ rẹ, ko gbe e, ibẹruboju gbọkan awọn alakooso ere ọhun, ni wọn ba wa a lọ si iletura to de si, wọn ja ilẹkun wọle, oku arabinrin naa ni wọn ba ninu yara. Oju-ẹsẹ ni wọn si gbe e lọ si yara igbooku-si, nileewosan Jẹnẹra ilu Ilọrin.

 

Oloogbe Olufunkẹ jẹ ọmọ bibi Ijebu-Ode, nipinlẹ Ogun, ti wọn si ti pe awọn alaṣẹ ere idaraya nipinlẹ Ogun lati fi iṣẹlẹ naa to wọn leti. Ọjọ Aiku, Sannde, ọṣẹ yii, ni wọn gbe oku naa lọ si ipinlẹ Ogun, lọdọ awọn mọlẹbi rẹ.

Asekaagba ere idaraya ọhun to yẹ ko waye ni wọn ti sun siwaju di ọjọ Aiku, Sannde, ọṣẹ yii, lati fi bu ọla fun oloogbe.

Leave a Reply