Wọn ba oku ọmọ Naijiria to n kẹkọọ niluu oyinbo ninu yara rẹ

Adewale Adeoye

Awọn alaṣẹ ijọba orile-ede Gẹẹsi ti lawọn maa ṣayẹwo daadaa sokuu ọmọ orilẹ-ede wa kan, Ọpẹyẹmi Adedipe, ẹni to n kẹkọọ lati gboye keji ninu imọ ẹrọ lorileede naa, to si tun ṣiṣẹ oṣu kekere nileeṣẹ kan lati maa fi ran ara rẹ lọwọ lati le mọ ohun to ṣokunfa iku ẹ.

Wọn ni niṣe ni wọn ba oku oloogbe naa ninu yara rẹ lẹyin ti awọn ẹlẹgbẹ rẹ ti ko ri i ko wa sibi iṣẹ lọ wo o nile.

ALAROYE gbọ pe ẹkọ imọ nipa kọmputa ni Ọpẹyẹmi n kọ nileewe giga ‘Lancaster University’.

Ẹnikan to mọ ọmọkunrin yii to tufọ iku rẹ lori ẹrọ abẹyẹfo, Twitter, sọ pe oloogbe naa ko saisan, ko si si ami pe nnkan kan n ṣe e, nitori oun ṣi ba a sọrọ ni wakati diẹ si asiko to ku ọhun. O fi kun un pe awọn mọlẹbi rẹ lati Naijiria paapaa pe e, ti wọn si ba a sọrọ nirọlẹ ọjọ to ku ọhun.

Awọn ẹlẹgbẹ ọmọkunrin naa ti wọn jọ wa nibi iṣẹ ti wọn ko ri i ni wọn wa a lọ sile, ti wọn si ba oku ẹ ninu yara to n gbe.

Okan lara awọn ọrẹ oloogbe naa to gbe iroyin iku ọrẹ rẹ sori ẹrọ ayelujara sọ pe, ‘Pẹlu ibanuje ọkan ni mo fi gbọ pe ọrẹ mi, Ọpẹyẹmi Adedipe Emmanuel, ku sinu yara rẹ. O n kẹkọọ onipo keji (Masitaasi) lọwọ nipa imọ ijinlẹ ẹrọ kọmputa nileewe fasiti kan lorile-ede Gẹẹsi, bẹẹ lo tun n ṣi ọlude nileeṣẹ kan ti wọn n pe (Centre for Ecology and Hydrology), iyẹn ẹkọ nipa omi ati bo ṣe n lọ kaakiri agbaye. Awọn ọrẹ rẹ kan ti wọn ko ri i ko wa sibiiṣẹ lo wa a lọọ sile, ti wọn si ba oku rẹ nilẹ nibi to ku si.

Ohun to jẹ kọrọ iku oloogbe naa dun mi ni pe ko pẹ rara sigba temi pẹlu rẹ sọrọ ti wọn tun fi pe mi pe Ọpẹyẹmi ti ku.

Awọn ọlọpaa agbegbe ibi to n gbe ti ṣeleri pe awọn maa ṣayẹwo sokuu rẹ lati mọ ohun to pa a gan-an.’’

Leave a Reply