Ọdọmọkunrin agbabọọlu kan ti orukọ rẹ n jẹ Richard Gyamfi yoo rojọ gidi ko too le bọ lọwọ awọn ọlọpaa lori odidi ori eeyan mẹta ti wọn ba ninu ẹrọ amomitutu (fridge) ninu ile rẹ to wa ni Sunyani Municipality, ni Gbana.
Gẹgẹ bi ileeṣẹ tẹlifiṣan kan ti wọn n pe ni Ibra Tv ṣe sọ, ọkunrin to tun maa n sọrọ nipa ere bọọlu, ti inagijẹ rẹ n jẹ ‘Fire Man’ yii ni wọn ni wọn fẹsun ipaniyan kan, ni wọn ba lọ sile rẹ pe ki wọn lọọ yẹ ibẹ wo. Iyalẹnu lo jẹ nigba ti wọn ṣi firiiji to wa ninu ile rẹ, ti wọn si ba ori eeyan mẹta nibẹ.
Ọmọ ọdun mẹtala kan ti wọn lo wa ninu awọn ti Richard pa, Louis Agyemangi, ni wọn lo dọgbọn tan lati ori papa ti wọn ti n gba bọọlu lọ si ile rẹ, to si pa ọmọ naa gẹgẹ bi awọn obi ọmọkunrin yii ṣe sọ.
Baba ọmọ to pa yii, Ọgbẹni Thomas Agyei, ṣalaye fawọn ọlọpaa pe nigba ti awọn ko ri ọmọ awọn, Louis Agyemangi, ko wale ni awọn bẹrẹ si i wa a. Lasiko tawọn n beere rẹ kaakiri ni ọrẹ rẹ kan, Tweneboa, sọ fawọn pe oun ri i pẹlu Richard to maa n gba bọọlu ti wọn tun n pe ni ‘Fire Man’.
Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ nigba ti awọn obi ọmọkunrin yii de ọdọ Richard, ti wọn si beere ọmọ wọn ti wọn ni o wa lọdọ rẹ. Niṣe lo sẹ kanlẹ pe ko sohun to jọ bẹẹ, o loun ko tiẹ foju kan ọmọ yii. Ṣugbọn ọrẹ ọmọ yii ṣaa yari pe oun ri awọn mejeeji ti wọn n kọja lọ lọsan-an ọjọ iṣẹlẹ yii.
Eyi lo mu awọn obi ọmọ yii sọ pe ko mu awọn niṣo nile rẹ. Nigba ti wọn debẹ, ọkan ninu awọn ilẹkun ile rẹ wa ni titi. Ni wọn ba beere kọkọrọ, ṣugbọn Richard ni kọkọrọ ilẹkun naa ti sọnu.
Awọn obi yii ko beṣu-bẹgba, wọn ke si awọn ọmọọta, lawọn yẹn ba ba wọn fipa ja ilẹkun ile naa. Ohun ti wọn si ri ya wọn lẹnu. Louis Agyemangi, ọmọ wọn ọkunrin ti wọn n wa ni wọn ba to dubulẹ gbalaja sinu agbara ẹjẹ, ti wọn si ti ge ori rẹ kuro.
Awọn ọmọọta yii ni wọn kọkọ lu u daadaa ki wọn too fa a le awọn ọlọpaa lọwọ. Awọn agbofinro naa ṣayẹwo sile rẹ, wọn ba ẹya ara eeyan to ko sinu apo saka, bẹẹ ni wọn ba ori eeyan mẹta ninu firiiji rẹ, ninu eyi ti Louis tawọn obi rẹ n wa wa.
Wọn ti ko awọn ẹya ara atori naa lọ si mọṣuari gẹgẹ bi Tẹlifiṣan Ibra ṣe fidi rẹ mulẹ.