Monisọla Saka
Gẹgẹ bi aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan lorilẹ-ede yii, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ati igbakeji rẹ, Kashim Shettima, ṣe n palẹmọ lati gba ipo iṣakoso ilẹ Naijiria, eyi ti yoo waye lọjọ Aje, Mọnde ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, oriṣiiriṣii eto ni wọn ti la kalẹ, pupọ ninu ẹ lo si ti n lọ lọwọ.
Lara rẹ ni ayẹyẹ tawọn olorin atawọn amuluudun mi-in ṣe fun Tinubu, ni papa iṣere MKO Abiọla, niluu Abuja.
Awọn olorin bii Wasiu Alabi Pasuma, Wande Coal, KCEE, Zinoleesky, atawọn mi-in ni wọn da awọn eeyan laraya lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii.
Nigba ti ọkunrin olorin taka-sufee nni, Habeeb Okikiọla ọmọ Ọlalọmi, tawọn eeyan mọ si Portable, n sọrọ lori idi ti ko fi kopa ninu eto ọhun. O ni owo ti wọn fi lọ oun kere si iye ti wọn ni ki wọn san foun, nitori bẹẹ loun ko ṣe yọju sibẹ lati ba Aṣiwaju dawọọ idunnu.
Ori ikanni Instagram rẹ ni ọkunrin olorin Zaazuu yii ti ni, “Zaazuu, wọn ti gba mi o. Emi ni mo kọrin, ‘Akoi Tinubu ẹja lo nibu’. Ṣebi Obi lẹ n dibo fun? Tinubu waa wọle, gbogbo awọn eeyan radarada yẹn wa lọ n ṣere fun un, ki i ṣe emi ni mo gbe Tinubu jade ni?
Bo ṣe di pe wọn pe Manija mi niyẹn o. Wọn ni ki n waa ṣere fun wọn nibi ayẹyẹ ọhun l’Abuja. Miliọnu mẹwaa Naira ni wọn ko silẹ gẹgẹ bii owo iṣẹ mi, amọ miliọnu marun-un Naira lo maa de ọwọ emi Portable.
“Bi mo ṣe yari niyẹn o, mo binu ya iwe yẹn danu ni. Mo tun binu pa nọmba ti wọn fi pe mi rẹ lori foonu, abi ṣe wọn n tan Jesu ni? Nnkan ti o jẹ kẹ ẹ ri mi nibi ayẹyẹ Abuja yẹn niyẹn o.
Ki wọn ma gbogo lori iṣẹ mi o.
Ẹ fi ti Zazuu fun Zazuu o”.
O ni nigba ti iye owo ti wọn gbe silẹ foun jẹ miliọnu mẹwaa Naira, ti awọn kan waa yọ miliọnu marun-un sẹyin, to jẹ pe aabọ yooku ni wọn fẹẹ foun toun ṣe wahala loun ko ṣe lọ.