Faith Adebọla, Eko
Awọn ọdọ kan ti inu n bi buruku buruku lori iṣẹlẹ to ṣẹlẹ lalẹ ọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, nibi ti awọn ṣọja ti yinbọn pa awọn ọdọ ti wọn kora jọ pọ ni Lẹkki ti fẹẹ dana sun ile mọlẹbi Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, to wa ni Omididun Street, ni Lagos Island.
Ni nnkan bii aago meje aabọ aarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii ni awọn ọdọ naa kora wọn jọ si agbegbe ile yii, ti wọn si n mura ati jo o kanlẹ.
Okuta, igi, irin atawọn nnkan mi-in ni wọn bẹrẹ si i ju ba ile naa, wọn fọ awọn gilaasi oju windo, wọn si ba waya ina to wọ ile naa jẹ.
Awọn ọdọ ọhun ni wọn ni wọn ti tu bẹntiroolu yi ile naa kan, ki wọn dana sun un lo ku ti awọn eeyan to wa laduugbo naa fi n bẹ wọn pe ki wọn ma ṣe bẹẹ nitori ọpọlọpọ ile to wa nitosi ni yoo ṣakoba fun.
Ibinu pe wọn ko ri ile yii sun ni wọn fi berẹ si i ju okuta lu windo ile naa ti wọn si fọ awọn gilaasi ile naa, ti wọn ba oriṣiiriṣii nnkan jẹ nibẹ.