Ọlawale Ajao, Ibadan
Ori lo ko baale ile kan, Tajudeen Olufade, yọ nigboro Ibadan laipẹ yii pẹlu bi awọn araadugbo to n gbe ṣe yọ àdá ati oríṣìíríṣìí ohun ìjà oloro ti i nigba ti iyawo ẹ kigbe ole le e lori.
Oníkóńdó ti yọ kóńdó, oníkùmọ̀ ti yọ kùmọ̀, ẹni tó ladaa ninu ile sí ti mu un jáde si ọkunrin naa ki wọn tóo mọ pe araadugbo awọn níbẹ ni i ṣe, ati pe iyawo ile ẹ, Bukọla Onifade, náà ló pariwo ole le e lori.
Nitori eyi atawọn iwa àkóbá mi-in tiyawo ẹ n hu si i ninu ile lo mu un gba kootu ibilẹ Ile-Tuntun to wa laduugbo Mapo, n’Ibadan, lọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, to kọja, o ni kile-ẹjọ ya oun ya obinrin naa.
Gẹgẹ bi ọkunrin telọ yii ṣe ṣalaye níwájú igbimọ awọn adajọ kootu naa, “Ile mẹrin ọtọọtọ lawọn lanlọọdu ti le wa jade nitori bi iyawo mi ṣe máa n ba mi já ninu ile lojojumọ, to sí máa n ba awọn araadugbo fa wahala.
“O pẹ kí n tóo dé lati ibi iṣẹ lọjọ kan, mo ba n kanlẹkun nigba ti mo dele lalẹ. Ṣugbọn kàkà kí iyawo mi ṣilẹkun fun mi, ariwo ole lo pa le mi lori. Awọn araadugbo pa mi tan lọjọ náà, diẹ ló kù.”
O waa rọ ile-ẹjọ lati fopin si igbeyawo ọdun mọkanla naa, ki wọn si yọnda awọn ọmọ wọn mejeeji fún oun lati maa tọju.
Bo tilẹ jẹ pe olujẹjọ ko fara mọ ki ile-ẹjọ fi ipinya sí àárín òun àti ololufẹ ẹ, obinrin onisowo yii fẹsun àìníkan-án-ṣe kan ọkọ ẹ, o ni ọ̀ọ́dúnrún (₦300) naira lọkunrin naa máa n fi silẹ gẹgẹ bíi owo ounjẹ òun atawọn ọmọ awọn lojoojumọ”.
Oloye Henry Agbaje ti í ṣe adajọ agba nile-ẹjọ ibilẹ ọhun ti fopin sí igbeyawo ọdun mọkanla naa.
O waa pàṣẹ fún olupejo lati máa san ẹgbẹrun mẹwaa naira loṣooṣu fún ìtọ́jú awon ọmọ mejeeji to da wọn po.