Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Bii ere ori itage lọrọ ri ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, laarin ọga agba yunifasiti tijọba apapọ niluu Oye-Ekiti, Purofẹsọ Abayọmi Fashina, atawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti wọn waa mu un lati Alagbọn, niulu Eko.
Awọn akẹkọọ fasiti ti ọrọ naa ṣoju wọn sọ f’ALAROYE pe awọn ọlọpa bii meje ti wọn dihamọra ni wọn de si ọgba ile-iwe naa latilu Eko, ni deede agogo mẹrin ọsan ọjọ yii, lati waa fi pampẹ ọba mu ọga agba ọhun lori lẹta ifẹhonu han kan ti awọn olukọ fasiti naa atawọn oṣiṣẹ ibẹ kọ sawọn ọlọpaa. Ẹsun ikowojẹ ni wọn fi kan ọga wọn yii.
Wọn ni lẹyin oṣu kẹrin to ti gba ipo ọga agba yunifasiti naa, o tun n gba owo ni yunifasiti ti ipinlẹ, niibi to ti n ṣiṣẹ tẹlẹ ko too gba ipo ọga agba fasiti tijọba apapọ niluu Oye.
Wọn ni bawọn ọlọpaa yii ṣe de geeti ọgba ile-iwe naa, ti wọn ni awọn wa lati ilu Eko lati waa ṣe iwadii ẹsun ikowojẹ atawọn ẹsun mi-in ti wọn fi kan ọga agba yii, lọgan lawọn ẹṣọ wọnyi sọ pe awọn ko ni i gba ki wọn wọnu ọfiisi ọga agba yii, ayafi ti wọn ba lọọ sọ fun un pe awọn ọlọpaa n beere ẹ. Ṣugbọn lẹyin alaye ati awuyewuye yii, awọn ọlọpaa naa fagidi wọle, bo tilẹ jẹ pe wọn ko mọ pato ibi tọfiisi rẹ wa.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọrọ bi ọga yii ṣe n gbowo oṣu lọna meji yii ti kọkọ di awuyewuye nigba ti wọn n ṣe ifọrọwanilẹnuwo lati yan an sipo to wa ọhun.
Ọkunrin yii ni wọn lo wa ninu ọfiisi rẹ lasiko tawọn agbofinro yii kọkọ de si ayika ọgba naa, wọn ni awọn oṣiṣẹ rẹ kan ni wọn dọgbọn fẹyin pọn ọn jade, inu igbo ṣuuru kan to wa layiika ọgba ọhun ni wọn lo lọọ ba mọ, ki wọn to waa fi mọto kan ti ko ni nọmba idanimọ gbe e jade nigba to ya.
Lẹyin tawọn ọlọpaa naa ti wa a fun ọpọ wakati ni wọn fibinu ko marun-un lara awọn ẹṣọ fasiti yii si mọto ti wọn gbe wa, wọn si wa wọn lọ, wọn lawọn ko ni i fi wọn silẹ afi ti wọn ba wa ọga fasiti ọhun jade.
Nigba to n fesi lori iṣẹlẹ yii, Olubadamọran lori eto iroyin si ọga agba naa, Ọgbẹni Folusho Ogunmọdẹde, sọ pe igbesẹ ati ihuwasi awọn ọlọpaa yii ko yatọ si tawọn ajinigbe, o ni niṣe ni wọn fẹẹ ji ọga agba naa lọ.
Ẹ oo ranti pe ni kete ti ọga agba yii gba ipo ọhun lo yọ ọga agba lẹka eto igbaniwọle sileewe naa nipo, bẹẹ lo tun yọ olusiro owo agba, Arabinrin Bọlatito Akande nipo, to si fi ẹsun ikowojẹ kan awọn mejeeji.