Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, ni awọn agbebọn kan ji iyaale ile kan gbe, Salimot Ajibọla, ti wọn si fi ọmọ ati ọkọ rẹ silẹ ninu mọto.
Gẹgẹ bi akọroyin iweeroyin Vanguard sẹ sọ, lasiko tawọn mọlẹbi naa fẹẹ wọnu ile wọn ni awọn agbebọn yii yọ si wọn ni agbegbe Rounder, l’Abẹokuta, nipinlẹ Ogun.
A gbọ pe obinrin yii pẹlu ọkọ ati ọmọ rẹ kekere pẹlu ọmọọdọ wọn ni wọn jọ wa ninu mọto ti wọn n lọ sile. Lojiji ni awọn agbebọn naa yọ si wọn. Ọkọ obinrin yii ni wọn kọkọ fi nnkan gba lori, ti iyẹn si daku rangbọndan, ti ko mọ ohun to n ṣẹlẹ mọ. Lasiko naa ni wọn ji iyawo rẹ gbe sa lọ, ti wọn si fi ọmọ wọn kekere ati ọmọọdọ silẹ.
Nigba ti ọkunrin yii ji pada saye lo ri i pe wọn ti gbe iyawo oun lọ. Lẹyin naa ni awọn agbebọn yii pe ọkọ obinrin yii, ti wọn si beere miliọnu mẹẹẹdọgbọn Naira lọwọ rẹ.
Lasiko idunaadura ni wọn gba lati gba miliọnu mẹẹẹdogun, ki wọn too waa pada gba miliọnu mẹta Naira lọwọ wọn.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, ṣugbọn o ni oun ko mọ nipa pe wọn gbowo lọwọ awọn eeyan naa.