Aderounmu Kazeem
Adajọ ti ni ki wọn sọ Kayọde Ṣeun, ẹni ọdun mejidinlọgbọn to ji awọn ọmọleewe girama mẹta gbe l’Ekiti, sẹwọn gbere.
Ile-ẹjọ giga kan niluu Ado Ekiti, lọkunrin yii ti gba idajọ ọhun. Ewọn gbere ni wọn sọ ọ si.
Olupẹjọ ijọba, Wale Fapohunda, sọ pe awọn mẹta ni wọn jọ huwa buruku naa, ṣugbọn awọn meji ti salọ, ati pe ọjọ keji oṣu karun-un, ọdun 2018, gan-an ni wọn huwa ọhun niluu Ayetoro-Ekiti, nijọba ibilẹ Ido/Osi.
Ọkan ninu awọn ọmọ ọhun sọ pe lasiko ti awọn wa ni isinmi ranpẹ ninu ọgba ileewe awọn lawọn ọkunrin mẹta ọhun kọlu awọn, ti wọn si fi aṣo di awọn lẹnu ki awọn eeyan too waa gba awọn silẹ.
Lẹyin ti Adajọ Abiọdun Adesọdun ti gbọ ọrọ lẹnu awọn agbẹjọro mejeeji, lo sọ pe pẹlu gbogbo ẹri to wa niwaju oun, loootọ ni awọn eeyan ọhun ji awọn ọmọleewe girama naa gbe.