Adewale Adeoye
Iwaju Onidaajọ M Midashiru, tile-ẹjọ Magisireeti kan to wa lagbegbe Iyaganku, niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, ni wọn foju baale ile kan, Ọgbẹni Dickson Peter, ẹni ọdun marundinlogoji ba. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o kina bọ ile lanlọọdu rẹ, Ọgbẹni Cepas Okeme, lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, o si jo gbogbo ile naa deeru patapata.
Ọlọpaa olupẹjọ, Insipẹkitọ Fẹmi Oluwadare, to foju olujẹjọ bale-ẹjọ sọ niwaju adajọ pe, ‘Oluwa mi, lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni olujẹjọ, Ọgbẹni Dickson, nija kekere kan pẹlu lanlọọdu rẹ, Ọgbẹni Cepas, kawọn araale ibi ti wọn n gbe too mọ ohun to n ṣẹlẹ, olujẹjọ yii ti kina bọ ile lanlọọdu rẹ. Ina ọhun jo gbogbo ile lanlọọdu yii kanlẹ patapata lọjọ naa, iye dukia to jona mọle jẹ miliọnu mẹfa aabọ Naira, nitori bi wọn ko ṣe tete ri ina ọhun pa. Ina naa tun ran de ile keji, to si tun jo gbogbo ile naa, dukia to jona nile keji jẹ miliọnu mẹta aabọ Naira.
Onidaajọ ko gba ẹbẹ rẹ rara, o ni ki wọn lọọ fi olujẹjọ pamọ sọgba ẹwọn Abolongo, to wa niluu Ọyọ, o sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹtalelogun, oṣu Keje, ọdun yii.