Faith Adebọla, Eko
Bawo lori lagbari eeyan ṣe dohun teeyan n ri he ninu kọta bii beba daya? Ibeere yii lawọn eeyan n beere latari bi afurasi ọdaran kan ti wọn porukọ ẹ ni Rasaki Aṣiwaju, ẹni ọdun marundinlogoji, tawọn agbofinro mu, ti wọn si ba korofo agbari eeyan mẹta lọwọ ẹ, ṣe sọ pe oun o paayan o, oun o si lọọ hu oku olokuu, o ni inu gọta loun ti ri awọn agbari mẹtẹẹta naa he, oun o mọ bo ṣe debẹ o, amọ oun nilo wọn ni toun loun fi ko wọn.
Wọn ni Rasaki n ko awọn agbari naa lọ sibikan to loun ti fẹẹ lo wọn lo fi ko sakolo awọn ọlọpaa ipinlẹ Eko, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii.
Awọn ọlọpaa naa ni wọn da a duro lọna, wọn lawọn fẹẹ wo ẹru to gbe di sinu lailọọnu baagi dudu kan, ṣugbọn o ni ko si ẹru ofin nibẹ, awọn nnkan iṣegun toun fi n ṣe aajo lasan lo wa nibẹ, bo tilẹ jẹ pe wọn fi dandan le e pe ko tu u.
Titu ti wọn lọkunrin naa tu baagi ọhun desalẹ, lo jẹ agbari eeyan mẹta lo ko sibẹ.
Njẹ ko ṣalaye ohun tawọn agbari naa n ṣe, niṣe lo bu sẹkun gbaragada bii ọmọde, o ni ki wọn ṣaanu oun, oun ri wọn he ni o, inu gọta loun ti ri wọn, oun o ji wọn ko o, bẹẹ ni wọn lo n tara para pe aye oun ti bajẹ, oun ti daran.
Ninu fọran fidio kan ti Ọlaoluwa fi soju opo tuita rẹ lori ẹrọ ayelujara, o ṣafihan afurasi ọdaran ọhun bo ṣe bu sẹkun ninu ṣaati alawọ buluu ati turọsa alawọ amọ̀ (brown) to wọ, bẹẹ lo n dọwọ bo oju rẹ, to n pariwo pe aye oun ti bajẹ.
O ni, “Ẹ ṣaanu mi o, baba mi ti ku, baba mi ti ba temi jẹ ko too lọ, mo ri awọn ori oku yii he ninu gọta laaarọ yii ni o, agbegbe Ayọbọ, ni Ipaja, ni mo ti ri wọn he. Haa, aye mi ti bajẹ o, temi ti bajẹ o.
O tun ni: “mi o ko wọn lọ sibi kankan o, emi ni mo fẹẹ lo wọn, mo fẹẹ lo wọn fun ara mi ni o. Mo mọ pe mo ti lufin, ẹ jọọ, ẹ ṣaanu mi, aajo ara mi ni mo ni ki n ṣe o.”
Amọ, ọkan ninu awọn to ri fidio yii kọ ọrọ sabẹ fọran naa lori ikanni tuita ọhun pe kawọn ọlọpaa ṣewadii daadaa, tori itẹkuu kan wa ti ko jinna si agbegbe ti afurasi ọdaran naa loun ti ri ori oku he yii. O ni afaimọ ni ki i ṣe pe niṣe lo lọọ hu awọn ori oku olokuu ninu saare, to waa n dibọn pe inu gọta loun ti ri wọn he.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O ni Rasaki ti wa lakata awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, ni Yaba, lori ẹsun yii. O lawọn ti n ba iwadii to lọọrin niṣo, ati pe abọ iwadii ni yoo pinnu igbesẹ ofin to kan lori iṣẹlẹ yii.