Awọn eleyii maa n fipa ba awọn obinrin laṣepọ lẹyin ti wọn ba ji wọn gbe tan

Monisọla Saka

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Rivers ti tẹ awọn afurasi ọdaran mẹta kan to jẹ pe fifi ọgbọn tan awọn obinrin lati le ji wọn gbe ni wọn maa n ṣe, lẹyin ti wọn ba ji wọn gbe ni wọn yoo tun fipa ba wọn lo pọ ti wọn ba ti ja wọn lole tan.

Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Rivers, SP Grace Iringe-Koko, ṣalaye pe awọn afurasi mẹtẹẹta yii, Ikechi Promise, Darlington Obi, ati Nwaobiri, ni ikọ C4I ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Rivers fi panpẹ ofin gbe.

Ninu alaye ẹ, Promise ati Obi ni wọn kọkọ fofin gbe ni nnkan bii aago mẹjọ aabọ alẹ ọjọ kẹfa, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, lẹyin ti wọn ji obinrin ẹni ọdun mejidinlọgbọn kan gbe loju ọna Okoha, Iwofe, logunjọ, oṣu Kejila, ọdun to kọja.

O ni inu ọja Igwurita ni wọn kọkọ tan ọmọbinrin naa lọ, nibẹ ni wọn ti ji i gbe lọ si Chokocho Pipeline, to wa nijọba ibilẹ Etche, nibi ti gbogbo awọn gidigannku ọhun ti fipa ba obinrin yẹn lajọṣepọ lẹyọkọọkan. Lẹyin naa ni wọn gba foonu kan ti wọn n pe ni iPhone, meji lọwọ ẹ, ati foonu Samsung kan.

Wọn tun gba ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta Naira (600,000) owo itusilẹ lọwọ awọn mọlẹbi ẹ, ko too di pe wọn fi i silẹ lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kejila, ọdun 2022.

Iringe ni, “Awọn afurasi yii jẹwọ pe ọgbọn tawọn maa n da ni lati tan awọn obinrin yii lori ikanni ẹrọ ayelujara kan ti wọn n pe ni Tinder, nibẹ lawọn ti maa n dẹnu ifẹ kọ wọn.

‘‘Lẹyin ọpọlọpọ itọpinpin ati ọpọlọpọ wahala, wọn ri olori awọn ikọ yii, Promise Nwaobiri, ẹni ọdun mejilelọgbọn, mu lagbegbe Choba, niluu Port Harcourt, lọjọ kẹsan-an, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ni deede aago kan ọsan”.

Agbẹnusọ ọlọpaa yii tẹsiwaju pe awọn ṣi n ṣakitiyan lati ri awọn ọmọ ẹgbẹ wọn yooku to ti sa lọ mu. O ni ileeṣẹ ọlọpaa ṣakiyesi pe lẹnu ọjọ mẹta yii pe ọrọ nipa awọn obinrin ti wọn n fi foonu tan lati ji wọn gbe n ja ran-in nigboro. Wọn waa rọ awọn obinrin lati ṣọra fun ajọṣepọ ati ifẹ ori ẹrọ ayelujara to le fa ki wọn rinrin ajo lọọ ba ẹni ti wọn ko mọ tabi ti wọn ko ti i ri ri.

With pix

Leave a Reply