Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Awọn baba agbalagba meji kan lọwọ tẹ laaarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, nibi ti wọn ti n gbiyanju ati hu oku olokuu ni iboji awọn Musulumi to wa laduugbo Surulere, niluu Ondo.
Ọkan ninu awọn tọwọ tẹ ọhun, Abraham Lasisi, ni wọn lo n sọ iboji oku naa, oun ni wọn lo gbimọ-pọ pẹlu ekeji rẹ, Ọladiran Adegoke, lati lọọ maa yọ awọn ẹya ara oku ti wọn sin sinu ọgba naa.
Baba ọlọdẹ ọhun lawọn eeyan kọkọ ṣakiyesi to n rin regberegbe layiika iboji ọhun laaarọ ọjọ naa, igba tawọn eeyan sun mọ ọn lati beere ohun to n wa ni wọn ba ekeji rẹ nibi to ti n gbẹ ilẹ lọwọ lai si oku to fẹẹ sin.
Nigba ti wọn si beere ohun to fẹẹ fi ilẹ to n gbẹ laarin ibojì ṣe, esi to fun wọn ni pe ọmọ ọdun meji aabọ kan to ku loun n ba wọn gbẹ ilẹ ibi ti wọn fẹẹ sin in si.
Ohun to kọkọ sọ fun wọn ní pe oku ọmọ naa wa ni mọsuari ileewosan ijọba to wa niluu Ondo, nigba ti wọn si fẹẹ fipa mu un pe ko mu awọn lọ sibẹ, ṣe lo tun yi ọrọ rẹ pada to ni wọn ti lọọ sin ọmọde naa si ẹgbẹ ile awọn obi rẹ.
Ọrọ awọn mejeeji ti ko ba ara mu lo bi awọn ọdọ to wa nibi iṣẹlẹ ọhun ninu tí wọn fi bẹrẹ si i po ẹkọ iya fun wọn.
Eyi lo mu kawọn eeyan kan sare lọọ pe awọn ẹsọ Amọtẹkun ki wọn too lu wọn pa si aarin ọgba iboji ti wọn ka wọn mọ.
Baba ọlọdẹ ọhun tawọn eeyan mọ si Alaaji lo kọkọ sọrọ nigba t’ALAROYE n fọrọ wa a lẹnu wo lori ohun to mọ nipa ẹsun ti wọn fi kan awọn mejeeji.
O ni oun wa ekeji oun lọ sile laaarọ kutukutu ọjọ iṣẹlẹ naa lati sọ fun un ko le lọọ ko erupẹ iboji kan to ba wọn gbẹ lọjọ Abamẹta, Satide, kuro ninu yara ti wọn gbẹ iboji ọhun si laduugbo Akinwande, Surulere, niluu Ondo.
O ni ile rẹ ni wọn ti sọ fun oun pe inu ọgba iboji naa lo wa to n ṣiṣẹ lọwọ.
Asiko to ni oun tọpasẹ rẹ wa sibi to ti n ṣiṣẹ ni awọn eeyan kan ri oun, ti wọn si n beere ohun ti oun n wa.
Ọgbẹni Ọladiran ninu alaye tirẹ ni lati ọjọ Abamẹta, Satide, ni baba ọlọdẹ naa ti n sọ fun oun pe oun ni iboji miiran ti oun tun fẹẹ gbẹ ninu ọgba iboji to wa ni Surulere.
O ni ọjọ yii kan naa lo mu oun lọ sibẹ, to si fi ibi ti oun fẹẹ gbẹ ẹ si han oun.
Baba to n fi sàréè gbigbẹ sisẹ aje ọhun ni aisowo lọwọ oun lo ṣokunfa bi ohun ṣe tete ji lọọ siṣẹ naa laaarọ kutukutu ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.
O ni iboji kekere naa loun n gbẹ lọwọ ti oun ti ṣeesi ja sinu saree mi-in, ibi to si ti n wọna ati yanju ọrọ ara rẹ ni ọgọọrọ awọn eeyan ti ya bo wọn, ki wọn too fa wọn le awọn ẹsọ Amọtẹkun ẹka tilu Ondo lọwọ.
Aarọ ọjọ yii kan naa lawọn ẹsọ Amọtẹkun ti fa awọn mejeeji le ọlọpaa tesan Yaba, niluu Ondo, lọwọ fun ẹkunrẹrẹ iwadii.
Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni ko sohun ti wọn ka mọ awọn afurasi mejeeji lọwọ lasiko tọwọ tẹ wọn.
O fi kun un pe iwadii awọn ṣi n tẹsiwaju lati fidi okodoro iṣẹlẹ naa mulẹ.