Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Awọn ọrẹ mẹta kan, Onibọnoje Timilẹyin, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn (27), Bello Tunmiṣe, ẹni ọdun mẹrindilogun (16), ati Ahmed Ọlasunkanmi, toun jẹ ẹni ọdun mọkandinlọgbọn (29), ni wọn ti wa niwaju ile-ẹjọ Majisireeti kan niluu Ado-Ekiti bayii, nibi ti wọn ti n sọ tẹnu wọn lori ẹsun ṣiṣe ayederu kaadi idanimọ pe oṣiṣẹ ileewe giga poli to jẹ ti ijọba apapọ to wa ni Ado-Ekiti ni awọn.
Awọn mẹtẹẹta ọhun, ti wọn n gbe laduugbo Falẹgan, niluu Ado-Ekiti ni wọn foju bale-ẹjọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Karun-un, ọdun yii. Ẹsun meji to rọ mọ igbimọ-pọ ṣiṣẹ ibi ati titẹ ayederu kaadi idanimọ ileewe giga poli ni wọn fi kan wọn.
Agbefọba, Insipẹkitọ Olumide Bamigbade, ṣalaye pe ni nnkan bii aago mẹjọ aarọ ọjọ kọkanla, oṣu Karun-un, ọdun yii, lawọn ọdaran naa ko si panpẹ awọn agbofinro nileewe ijọba apapọ to wa ni adugbo Falẹgan, niluu Ado-Ekiti ọhun. O ni ẹṣẹ ti wọn ṣẹ yii lodi sofin, o si ni ijiya ninu.
Bakan naa lo bẹ ile-ẹjọ pe ki wọn fun oun laaye lati pe elerii wa siwaju adajọ. Lati le ko awọn ẹlẹrii yii jọ, o dabaa pe kile-ẹjọ ṣi ko awọn ọdaran naa pamọ si ọgba ẹwọn.
Nigba ti wọn n beere lọwọ awọn afurasi ọdaran naa boya wọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn, wọn lawọn ko jẹbi. Agbẹjọro wọn, Ọgbẹni Gbenga Ariyibi ati Ade Ademọla, bẹ ile-ẹjọ pe ki wọn fun awọn onibaara awọn ni beeli pẹlu ileri pe wọn ko ni i sa lọ, wọn yoo si maa wa nikalẹ titi ti igbẹjọ naa yoo fi wa sopin.
Ninu idajọ rẹ, Arabinrin Olubunmi Bamidele, faaye beeli silẹ fawọn ọdaran naa pẹlu ẹgbẹrun lọna aadọta Naira ati oniduuro kọọkan.
Lẹyin eyi lo sun igbẹjọ si ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii.