Faith Adebọla
Pẹlu bawọn eeyan o ṣe fi bẹẹ ri owo tuntun gba, debi ti wọn yoo ri i na, ori lo ko awọn oṣiṣẹ ileepo kan ta a forukọ bo laṣiiri yọ, diẹ lo ku ki wọn lu gudẹ lọwọ Joseph ati ọrẹ ẹ, Kenneth, ti wọn fẹẹ na ayederu owo tuntun ọhun fun wọn. Ẹgbẹrun lọna ọgọsan-an (N180,000), ni wọn ko dani ti wọn lawọn fẹẹ fi ra epo, bẹẹ feeki ni gbogbo owo naa, lọwọ ba tẹ wọn.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Enugu, DSP Daniel Ndukwe, to ju ọrọ yii sori afẹfẹ, lori ikanni agbọrọkaye rẹ sọ pe ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹta, oṣu Keji yii, lọwọ tẹ awọn mejeeji, Kenneth Onyeka Ezeja, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, to n gbe Iheakpu-Awka, nijọba ibilẹ Guusu Igbo-Eze, ati Joseph Chinenye, ẹni ọdun mọkandinlogoji, ti wọn loun n gbe lagbegbe Onicha-Enugu, nijọba ibilẹ Ariwa Igbo-Eze.
Wọn ni niṣe lawọn mejeeji kọkọ rin wọ ṣọọbu oni-POS kan pe ko ṣe transifaa ẹgbẹrun lọna ọgọsan-an si akaunti awọn, niyẹn ba sọ fun wọn pe oun o ni i gba owo atijọ o, owo tuntun tijọba ni kawọn maa fi ṣe ipaarọ loun fẹ, wọn ni ko buru, owo tuntun naa lo wa lọwọ awọn.
Ọlọrun lo ni ki oni-POS yii beere pe ki wọn jẹ koun kọkọ ri owo naa na, bi wọn si ṣe ko owo apo wọn jade, aganran ni wọn loootọ, amọ ara fun oni-POS, o loun o le ṣe tiransfaa fun wọn, ki wọn maa lọ.
Lẹyin tawọn afurasi yii ti rin jinna, wọn ya sileepo kan laduugbo Ibagwa-Akwa pẹlu ayederu owo to wa lọwọ wọn, wọn fẹẹ fowo naa ra epo bẹntiroolu, amọ lẹyin ti wọn ti ra epo tan, ti wọn sanwo, ni olutaja naa figbe ta, o l’ẹbu ni owo ti wọn ko foun, o si bu wọn laṣọ so, ibẹ si lakara ti tu sepo, lọrọ ba di tọlọpaa.
Alukoro ọlọpaa ni nigba tawọn yẹ awọn owo ti wọn n ko kiri ọhun, ẹgbẹrun kan Naira alawọ buluu, iru eyi tijọba ṣẹṣẹ ṣe ni gbogbo ẹ, aadọsan-an si ni.
O ni loootọ lowo naa tuntun nẹnẹ, o si n ta sansan bii aganra, amọ yatọ si pe awọ ara owo ọhun ko ja geere bii ojulowo, wọn ni nọmba owo kan naa lo wa lara awọn owo yii. Ọgọta ninu owo beba naa ni nọmba A/34:282656 delẹ, ọgọta mi-in tun ni A/46:5787759, nigba ti wọn kọ nọmba A/93:852942 sara ọgọta to kẹyin, bẹẹ nọmba ara owo Naira to ba jẹ ojulowo ki i papọ.
Wọn lawọn afurasi ọdaran yii ti jẹwọ pe loootọ lowo naa ki i ṣe ojulowo, ayederu ni, awọn lawọn tẹ ẹ, awọn si n dọgbọn ati na an laṣiiri fi tu.
Ṣa, Ndukwe ti ni kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Enugu ti paṣẹ ki wọn taari awọn ọbayejẹ yii siwaju adajọ tawọn ọtẹlẹmuyẹ ti wọn n tọpinpin iṣẹlẹ naa lọwọ ba ti pari iṣẹ wọn.
Bẹẹ ni agbofinro naa sin awọn araalu ni gbẹrẹ ipakọ pe ki wọn maa yẹ owo ti wọn ba n fun wọn wo, paapaa owo tuntun