Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Tẹgbọn-taburo kan, Monsuru Tajudeen ati Lawal Tajudeen, lọwọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti tẹ bayii lori ẹsun pe wọn n paayan ṣoogun owo.
Lagbegbe Yemọja, niluu Iwo, ni wọn ti mu awọn mejeeji, iwadii si fi han pe wọn ti lọwọ ninu ọpọlọpọ ipaniyan to ti waye sẹyin niluu naa, bẹẹ ni wọn ṣeku pa obinrin kan to n jẹ Mutiat Alani laipẹ yii.
Lẹyin ti aṣiri wọn tu ni awọn ọdọ agbegbe naa fibinu dana sun ile wọn pẹlu awọn ile mẹta mi-in to wa lagbegbe wọn.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni oriṣiiriṣii ẹya ara awọn eeyan meji ni wọn ba ninu ile ti awọn tẹgbọn-taburo naa n gbe.
Gẹgẹ bi Ọpalọla ṣe wi, ọkan lara awọn afurasi naa, Monsuru, jẹwọ pe aimọye eeyan lawọn ti pa, ṣe loun si maa n fi wọn ṣoogun.
Ọpalọla sọ siwaju pe nigba ti Mutiat Alani sọnu, ti wọn n wa a, lawọn ọlọpaa ṣewadii ibi ti ẹrọ ibanisọrọ rẹ wa, wọn si ri i pe ọwọ Monsuru ni, bayii lawọn ọlọpaa ya bo ile rẹ, ti wọn si ba ọpọlọpọ ẹya-ara eeyan nibẹ.
Nigba to n sọrọ nipa iṣẹlẹ naa, Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi, bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa, o ni ọdaran ati ọmọ ale ni ẹnikẹni to ba n hu iru iwa bẹẹ.