Faith Adebọla, Eko
Ọwọ ọlọpaa ti ba gende mẹta kan l’Ekoo, Bọlaji Elewuro, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, Emeka George, ẹni ọgbọn ọdun, ati ẹni kẹta wọn tọjọ ori ẹ kere ju lọ, Ahmed Balogun, ẹni ọdun mẹtalelogun. Wọn ni iṣẹ adigunjale ni wọn n fi ibọn ati mọto ti wọn ba lọwọ wọn ṣe.
Owurọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹrin yii, lọwọ ọlọpaa lati ẹka wọn to wa l’Ajah, tẹ awọn afurasi mẹtẹẹta, lasiko tawọn ọlọpaa naa n ṣe patiroolu wọn.
Inu ọkọ ayọkẹlẹ bọginni Honda City, alawọ eeru kan, eyi ti nọmba rẹ jẹ LAGOS GGE 288 GV, lawọn mẹtẹẹta wa, wọn ti ara wọn mọ ọkọ ọlọyẹ, orin n dun kikankikan ninu ọkọ naa, wọn fẹẹ gba abẹ biriiji Ajah kọja, lawọn oni-patiroolu ba fura si wọn, wọn si da wọn duro.
Gẹgẹ bi Benjamin Hundeyin ṣe ṣalaye ninu atẹjade kan to fi lede lori ọrọ ọhun, o ni igba tawọn agbofinro beere ibi ti wọn ti ri ọkọ naa, niṣe ni wọn n woju ara wọn, eyi lo mu ki awọn ọlọpaa pinnu lati yẹ inu ọkọ ọhun wo.
Ibọn oyinbo kan, katiriiji ọta ibọn mẹta ti wọn o ti i yin, atawọn nnkan ija oloro ni wọn ba nibẹ, ni wọn ba wọn gbogbo wọn sọkọ ọlọpaa, o di teṣan.
Teṣan lawọn afurasi naa ti jẹwọ pe iṣẹ adigunjale lawọn n ṣe, agbegbe Ajah si Lẹkki ni wọn lawọn ti n ṣọṣẹ, wọn lawọn ra ibọn naa ni.
Bọrọ yii ṣe n detiigbọ Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, Abiọdun Alabi, ti paṣẹ ki wọn fi wọn ṣọwọ si ẹka to n ṣọfintoto iwa idigunjale ni Panti, Yaba, ki iwadii to lọọrin le waye nipa wọn.
Alabi lawọn maa taari wọn siwaju adajọ laipẹ.