Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Pẹlu bawọn eeyan ṣe bẹrẹ si i ko ounjẹ kẹtikẹti ni Ṣagamu, Ijẹbu-Ode ati Ifọ, nipinlẹ Ogun lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ti wọn si ni ounjẹ to yẹ kijọba pin faraalu lasiko Korona ti wọn ko pin ni, Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, ti sọ pe ki i ṣe ile itọju ounjẹ ijọba ipinlẹ Ogun lawọn eeyan naa fọ, nitori ijọba oun ko tọju ounjẹ to yẹ ko pin faraalu.
Ọjọ Aje tawọn eeyan n gbe apo irẹsi atawọn ounjẹ onipaali lati inu awọn ile ẹru si kan ni Gomina Dapọ Abiọdun sọ eyi di mimọ. O ni awọn kan ni wọn wa nidii ibajẹ, ti wọn mọ-ọn-mọ fẹẹ ba orukọ awọn gomina jẹ, ti wọn n sọ kiri pe ile ounjẹ Korona lawọn eeyan n fọ, ati pe ijọba tọju ounjẹ to yẹ ki wọn pin fun araalu ni.
Gomina ṣalaye pe ajọ kan torukọ wọn n jẹ Coalition Against Covid-19(CACOVID), ko ounjẹ fawọn ipinlẹ kaakiri loootọ. O ni ninu oṣu kẹsan-an yii ni ipinlẹ Ogun ṣẹṣẹ gba tiẹ.
O fi kun un pe ajọ naa fi ilana tawọn yoo fi pin ounjẹ ọhun lelẹ, ilana naa lawọn si tẹle.
Pẹlu ilana ti CACOVID la kalẹ naa, gomina sọ pe ijọba ipinlẹ mejidinlogun(18) nijọba oun ti pin awọn ounjẹ naa fun ninu ogun ijọba ibilẹ to wa nipinlẹ Ogun.
Ọmọọba Abiọdun ṣalaye pe bi ko ba si ti iwọde SARS to tun fa idaduro ni, wọn ko ba ti pin awọn ounjẹ naa ju bẹẹ lọ.
‘‘Pe ẹnikan tọju ounjẹ iranwọ Korona pamọ yẹn ki i ṣe ootọ, ko sohun ti ko ba dun mọ awa gomina ju ka pin in lasiko to yẹ lọ. Ko si ile ẹru wa kankan nipinlẹ Ogun tawọn eeyan ya bo lati ko ounjẹ.
‘‘Bi mo ṣe n ba yin sọrọ lonii yii ( Mọnde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹwaa, 2020), a ti pin ounjẹ de ijọba ibilẹ mejidinlogun abi mọkandinlogun.’’ Bẹẹ ni Dapọ Abiọdun wi.
Ṣe lọjọ Mọnde yii ni awọn fidio ibi tawọn eeyan ti n ko ounjẹ oriṣiiriṣii jade bọ sori ẹrọ ayelujara, awọn to n ko ounjẹ ọhun si n darukọ agbegbe ti wọn wa nipinlẹ Ogun.
Ti Ṣagamu lo kọkọ gori afẹfẹ, ti Ijẹbu-Ode tẹlẹ, bẹẹ naa ni ti Ifọ.
Awọn eeyan naa n fo fayọ bi wọn ṣe n ko awọn ounjẹ ọhun ni, bẹẹ ni wọn n sọko ọrọ si gomina pe o tọju ounjẹ to yẹ ko pin faraalu lasiko Korona pamọ.
Wọn ni Ọlọrun ti ba awọn naa gba ẹtọ awọn bayii, o kuku pẹ tawọn ti n bẹ Ọlọrun pe ko fi ibi ti ile ounjẹ Koro wa nipinlẹ yii han awọn naa, gẹgẹ bi wọn ṣe ti ri i l’Ọṣun, Ekiti, Abuja, Jos, Eko ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Gbogbo awọn to gbọ ọrọ gomina ni wọn ni irọ ati awawi ti ko lẹsẹ nilẹ ni ọkunrin naa n sọ.