Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Titi dasiko ta a pari iroyin yii, ko ti i ṣeni to le sọ ibi ti oku awọn eeyan meji tawọn eeyan kan pa nile Oloye Sunday Adeyẹmọ (Igboho) l’Ọjọbọ, ọjọ kin-in-ni, oṣu keje, ọdun 2021 yii wa, bẹẹ ni wọn ko si mọ ibi ti wọn ko awọn mi-in ti wọn gbe lọ laaye paapaa si.
Niṣe lẹjẹ eeyan n ṣan nilẹ bala, tawọn eeyan n tẹ aarin ẹjẹ kọja nile Igboho to wa ni Soka, nipinlẹ Ọyọ, nigba ti awọn agbebọn kan ti wọn ni aṣọ ṣọja ni wọn wọ, ya bo ile naa laarin oru, ti wọn si ṣina ibọn bolẹ, ti wọn pa meji ninu awọn eeyan to n ba Igboho ṣiṣẹ, ti wọn ba ọpọlọpọ mọto to wa ninu ọgba ọkunrin naa jẹ, ti wọn si tun ko awọn kan lọ ninu awọn eeyan ti wọn ba ninu ile naa.
Kinni kan ti agbẹnusọ Igboho, Ọlayọmi Koiki, n tẹnumọ ni pe ṣọja Naijiria lawọn agbebọn to waa paayan nile Igboho. O ni o to ọgọrun-un kan ṣọja to ya bo ile naa, ko si din ni ọkọ awọn ologun meje ti wọn gbe wa.
Koiki fidi ẹ mulẹ pe ọmọ Yoruba meji ni wọn pa nile Igboho, o kọ ọ soju opo Fesibuuku rẹ pe awọn ko mọ ibi ti wọn gbe oku awọn eeyan naa lọ, awọn ti wọn si mu laaye naa, awọn ko ti i gburoo wọn.
Gbogbo ara ogiri ilẹ ni wọn fibọn fọ, kedere lawọn eeyan si n wo ọta ibọn nilẹ lẹyin ikọlu oru ganjọ naa nile Igboho.
Eyi kọ nigba akọkọ ti wọn yoo kọ lu Sunday Igboho to n ja fun idasilẹ orilẹ-ede Yoruba. Wọn ju ina sile rẹ loṣu kin-in-ni, ọdun yii, awọn DSS da a lọna loṣu keji, ni marosẹ Eko s’Ibadan, nigba to n lọ sile Baba Ayọ Adebanjọ, ko too tun kan eyi to ṣẹlẹ lọjọ akọkọ ninu oṣu keje yii.
Satide ọsẹ yii ti i ṣe ọjọ kẹta, oṣu keje, n’Ighoho atawọn eeyan rẹ n lọ s’Ekoo lati polongo ilẹ Olominira Yoruba ti wọn n ja fun. O ku ọjọ meji ti yoo rin irinajo naa ni ikọlu yii waye, awọn eeyan si ni ete ati di ọkunrin naa lọna Eko rẹ to fẹẹ lọ ni.
Igboho funra rẹ ko ti i sọrọ leyin ikọlu yii, ṣugbọn Koiki sọ pe alaafia lọga oun wa, o ni kinni kan ko mu un.