Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ni nnkan bii ọwọ irọlẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu keji, ni iroyin gba igboro pe awọn kan ti wọn fura si pe Fulani darandaran ni wọn, fi ina si ile agbara mọnamọna (Solar) to wa ni ilu Awowo, nijọba ibilẹ Ewekoro, nipinlẹ Ogun, wọn si jo o kanlẹ raurau.
Gẹgẹ bi Alawowo ti Awowo, Ọba AbdulGafar Ọlasunkanmi Tijani, ṣe wi, o ni awọn Fulani ni wọn sọna sile agbara Solar naa, eyi ti owo rẹ to ẹgbẹrun mẹẹẹdogun pọn-un bi a ba ṣi i ni owo oyinbo.
Ko sẹni to ri awọn to ṣiṣẹ ibi naa mu, nitori ko sẹni to mọ igba ti wọn sọna si ile agbara naa, ina ti n jiṣẹ ti wọn ran an kawọn ara ilu too ri i pe nnkan ti ṣe