Faith Adebọla
Gbajugbaja aṣaaju ẹsin Musulumi l’Oke-Ọya nni, Sheik Ahmad Gumi, ti sọ pe kawọn obi ati araalu lọọ fọkan wọn balẹ lori ọrọ awọn akẹkọọ Fasiti Greenfield mẹrindinlogun ti wọn ṣi wa lakata awọn ajinigbe ni Kaduna, o ni wọn maa too fi awọn naa silẹ laipẹ.
Ilu Kaduna ni Gumi ti sọrọ idaniloju naa fawọn oniroyin l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, nigba to n sọrọ nipa isapa toun ṣe ki wọn too ri awọn akẹkọ ileewe ijọba Federal College of Forestry, Afaka, tawọn agbebọn naa ṣẹṣẹ da silẹ gba l’Ọjọruu, Wẹsidee yii gba.
Awọn obi awọn akẹkọọ ti wọn tu silẹ ọhun ni wọn kora jọ, wọn lọọ dupẹ lọwọ Sheik Gumi, wọn lawọn waa fẹmi imoore han si i fun bo ṣe bawọn yọ ọmọ awọn lọwọ ahamọ ati iku.
Nigba to n fesi, o ni ọrọ ti n lọ lori awọn akẹkọọ Fasiti Greenfield ti wọn ṣi wa lahaamọ awọn agbebọn, wọn o ni i pẹ fi awọn naa silẹ.
“A ti n bawọn ajinigbe sọrọ lori tawọn akẹkọọ Fasiti Greenfield tawọn agbebọn ji gbe naa. Ṣe ẹ ranti pe wọn dunkooko pe awọn maa pa gbogbo wọn danu tawọn o ba ri owo lọjọ ti wọn fi gbedeke wọn si, ṣugbọn nigba ti a ti n ba wọn sọrọ, wọn ti n dẹwọ diẹdiẹ.
Tori naa, a dupẹ pe wọn o pa wọ mọ a ṣi n dunaadura pẹlu wọn lọwọ, mo si gbagbọ pe iṣẹlẹ ti awọn akẹkọọ Afaka yii maa jẹ ki wọn pero da, ki wọn gba pẹlu wa, ki wọn si tu awọn ọmọ naa silẹ.”
Nigba to n sọrọ lori bi aṣeyọri ti awọn ọmọ kọleeji Forestry mẹadinlọgbọn ṣe ṣee ṣe, o ni iṣẹ olulaja loun ati Aarẹ tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ṣe lori ọrọ naa, tori ki i ṣe oun tabi Ọbasanjọ ni wọn n ba ja, ijọba ati awọn agbebọn ni wọn n ba ara wọn fa nnkan.