Faith Adebọla, Eko
Ọga agba ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko (LASEMA), Dokita Olufẹmi Oke-Ọsanyintolu, ti ṣalaye pe gaasi idana kan to bu gbamu lojiji lo ṣokunfa ina nla kan to ṣọṣẹ lagbegbe Surulere, nipinlẹ Eko, lopin ọsẹ to kọja yii.
Owurọ ọjọ Aje, Mọnde, ni Oke-Ọsanyintolu ṣọrọ naa fawọn oniroyin nigba to n ṣalaye nipa abajade iṣẹ iwadii ti wọn ṣe.
O ni ẹri fihan pe ọkan lara awọn ọmọri ati okun ti wọn so mọ agolo afẹfẹ idana naa ti jẹra, to si ti n yọ jo. Bi kinni naa ṣe jo yii lo mu ki afẹfẹ naa gbina lojiji. Ohun to mu ko buru ni pe awọn eeyan to wa lawọn ṣoọbu naa ti lọ sile, to si tun jẹ oru niṣẹlẹ naa waye.
Bakan naa lo ni ijọba maa ṣayẹwo sawọn ile ti ina naa kan atawọn ti afẹfẹ ina naa rọ lu, lati mọ boya wọn ṣi bojumu fawọn eeyan lati gbe, tabi wọn ti di ẹgẹrẹmiti. Ṣaaju ni Adele Ọga agba fun ileeṣẹ panapana ipinlẹ Eko, Abilekọ Margaret Adeṣẹyẹ, ti sọ pe iwadii ti n lọ lọwọ lati mọ pato ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ to waye loru mọju ọjọ Aiku, Sannde ọhun, ninu eyi ti ọpọ dukia ati ọja ọpọlọpọ miliọnu naira ti ṣegbe.
O ni okunkun to kun dudu wa lara ohun to ṣediwọ lati tete mọ ohun to ṣokunfa ina yii, ko si jẹ ko rọrun lati pa a lasiko, tori ọganjọ oru lawọn gba ipe pajawiri nipa iṣẹlẹ buruku ọhun.
Adeṣẹyẹ ni loju-ẹsẹ lawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa lati ọfiisi awọn to wa ni Isọlọ ati Bọlade, ti dahun pada, ti wọn si kapa ina ọhun.
Ṣa, o fidi ẹ mulẹ pe ko si ofo ẹmi kankan ninu ijamba yii, bẹẹ ni ko sẹni to farapa.