Wọn ni Dapọ Ọjọra, ẹgbọn iyawo Bukọla Saraki, yinbọn para ẹ

Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ ni ariyanjiyan ṣi n waye lori iku ojiji to pa Ọgbẹni Dapọ Ọjọra, eni ti i ṣe ẹgbọn Toyin Saraki, iyawo aarẹ ile igbimọ aṣofin agba tẹlẹ, Dokita Bukola Saraki.

Lojiji ni wọn sọ pe awọn eeyan ti wọn jọ n gbe gbọ iro ibọn, nigba ti wọn yoo si fi sare de ibi to wa, ninu agbara ẹjẹ ni wọn ti ba Dapọ.

Ni kete ti iṣẹlẹ ọhun ti waye loriṣiriiṣii iroyin ti gba igboro, bi awọn kan ṣe n sọ pe niṣe ni ẹgbọn Toyin Saraki yii yinbọn funra ẹ lori, bẹẹ lawọn mọlẹbi n sọ pe ki i se pe o para ẹ o, aṣita ibọn lo pa a.

ALAROYE tunn gbọ pe ni nnkan bii ọdun mẹsan-an sẹyin ni Ọtunba Adekunle Ọjọra, eni ti i ṣe baba ọkunrin to yinbọn para ẹ yii ti kọkọ padanu ọmọ ẹ ọkunrin ti wọn pe orukọ ẹ ni Gbẹgi. Bakan naa ni wọn tun sọ pe, ori ti kọkọ ko Dapọ yii yọ lasiko to ni ijanba pẹlu ọkada olowo nla kan ti wọn n pe ni Power Bike ni nnkan bii ọdun meloo kan sẹyin.

Yatọ si eyi, lara ohun ti wọn sọ pe o tun n ko idaamu ọkan ba Dapọ, to fẹran ere idaraya Polo daadaa ni wahala to ni pẹlu igbeyawo ẹ.

Ṣugbọn lọdun to kọja ni wọn ni Dapọ yii ati iyawo ẹ ti wọn ti kọ ara wọn silẹ sin ọmọ wọn, Tara, lọ sile ọkọ, nigba ti eto igbeyawo waye laarin oun ati Fọlajimi Ayọdeji, ni Ikoyi, l’Ekoo.

Igbeyawo yii gan-an ni wọn sọ pe o fun wọn lanfaani lati yanju wahala to wa laarin wọn, ti aarin Dapọ ati Patricia si tun dọgba pada lẹẹkan si i.

Bi ọrọ ọhun ṣe wa niyẹn ki wahala too ṣẹlẹ lọjọ Ẹti, Furaidee,  nigba ti iro ibọn dun lojiji, ti Dapọ ọmọ Adekunle Ọjọra si dagbere faye pe o digbooṣe.

Ṣa o, minisita fun eto irinna ọkọ ofurufu tẹlẹ, Fẹmi Fani-Kayọde, ṣapejuwe Dapọ Ọjọra lori ikanni abẹyẹfo ẹ gẹgẹ bii ojulowo ọmọluabi to ṣe daadaa nigba aye ẹ, ni gbogbo aadọta ọdun ti awọn jọ lo papọ  gẹgẹ bii ọrẹ

Leave a Reply