Kọmiṣanna fun eto ilera nipinlẹ Eko, Ọjọgbọn Akin Abayọmi, ti sọ pe ara Gomina Babajide Sanwo-Olu, ti ya daadaa, ati pe ni kete ti esi ayẹwo ti wọn ṣe fun un ba ti jade ni ọkunrin naa yoo pada sẹnu iṣẹ ẹ.
Laipẹ yii lo fi ọrọ ọhun sori ikanni abẹyẹfo ẹ nigba to n sọ nipa ipo ti gomina naa wa lori arun koronafairọọsi to kọ lu u.
Ọjọ kejila, oṣu kejila, ọdun yii, ni arun Koronafairọọsi kọ lu Gomina Babajide Sanwo-Olu, latigba naa lo ti wa ni ipamọ, nibi ti wọn ti n tọju ẹ gidigidi.
O ni gomina naa ṣi n gba itọju, ati pe ni kete ti esi ayẹwo to ṣẹṣẹ ṣe ba ti fidi ẹ mulẹ pe kinni ọhun ko ṣe e mọ ni yoo darapọ mọ awọn araale ẹ atawọn oṣiṣẹ ẹ pada.
Ninu ọrọ ẹ naa lo ti dupẹ lọwọ awọn eeyan ipinlẹ Eko lori adura ti wọn n ṣe fun gomina naa ki ara ẹ le tete ya, bakan naa lo sọ pe o ṣe pataki ki awọn eeyan maa lo ibomu wọn bayii, paapaa lori bi arun ọhun tun ṣe n gbilẹ si i lasiko yii.