Faith Adebọla
Ọlọrun nikan lo mọ ibi ti wahala awọn Fulani darandaran atawọn agbẹ lagbegbe Ibarapa yii maa kangun si, pẹlu bi wọn ṣe ni olori awọn Fulani kan ti wọn n pe ni Iskilu Wakili lagbegbe Ayetẹ, ti lọọ sami sawọn ilẹ kan, o ta aṣọ pupa mọbẹ, o si lawọn Yoruba, awọn agbẹ, o gbọdọ kọja lapa ibi toun sami si ọhun, afi ti wọn ba fẹẹ r’iku he.
Ọkan ninu awọn agbẹ, to tun jẹ ẹṣọ fijilante lagbegbe naa, Ọgbẹni Babatunde Ọjẹwunmi, sọ f’ALAROYE pe niṣe lọkunrin ti wọn lo n fojoojumọ mura ija ọhun sọ ara rẹ di ẹrujẹjẹ sagbegbe naa.
O ni latigba ti Sunday Igboho (Sunday Adeyẹmọ gan-an lorukọ ẹ) ti waa le Seriki awọn Fulani kuro niluu Igangan ni Wakili ti n mura ati gbẹsan.
A gbọ pe niṣe lawọn Fulani n pọ si i, ti wọn si ti pin ara wọn kaakiri awọn oko atinu igbo to wa lagbegbe Kajọla, nibi ti Gaa Wakili wa pẹlu awọn maaluu rẹ.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, wọn ni Fulani to n sin maaluu rẹpẹtẹ yii ti ko awọn maaluu ati iyawo rẹ kuro lagbegbe naa, oun atawọn Fulani ti wọn mura ija ni wọn pin ara wọn sinu igbo, ti wọn ta aṣọ pupa mọ ara igi, lati sami sibi tawọn ti ki i ṣe ara wọn gbọdọ de duro. Wọn tiẹ royin pe awọn kan lara awọn Fulani naa tun n gun ori igi, kawọn to ba n kọja ma baa tete ri wọn titi ti wọn yoo fi fẹẹ ṣọṣẹ wọn.
Titi dasiko yii, gẹgẹ bi Ọba ilu Ayetẹ ṣe fidi ẹ mulẹ, ko ti i si agbẹ kan to le kọja soko, bẹẹ ni ibẹrubojo gba ọkan gbogbo araalu, ti wọn si n woju ijọba lati mọ igbesẹ tawọn maa gbe.
Ọrọ yii ni wọn lo mu kawọn ọdọ kan fẹhonu hàn lọjọ Tusidee, lẹyin ti Gomina Seyi Makinde ti kuro n’Igangan, lojo Aje, Mọnde, ọsẹ yii.