Titi di ana ode yii ni ariwo ṣi i n lọ, ti awọn eeyan ṣi n wadii lati mọ okodoro nipa aṣaaju ẹgbẹ oṣelu APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu. Iwe iroyin kan, The Page News Desk lo fọ kinni naa mọlẹ lọsẹ to kọja pe Aṣiwaju ti ko Korona, ati pe aisan naa ti gbe e wọnlẹ, o si wa ni orilẹ-ede France nibi to ti n gba itọju lọwọlọwọ. Ṣugbọn kia ni Tinubu ti jade, o ni oun ko ko Korona kankan, bo tilẹ jẹ pe oun ko si nile loootọ. Tunde Ibrahim ti i ṣe Alukoro fun Tinubu ṣalaye pe o ti to ẹẹmẹẹdogun ti ọga oun ti ṣe tẹẹsi lori arun Korona yii, ṣugbọn gbogbo tẹẹsi to ṣe lo fihan pe ara rẹ da, ko nilo itọju Korona rara. O ni irọ ni iwe iroyin naa n pa. Ṣugbọn ALAROYE fi idi rẹ mulẹ pe loootọ ni Aṣiwaju ko si nile, o ti wa ni orilẹ-ede France ka too wọnu ọdun tuntun rara, nibẹ lo wa ni gbogbo igba ti ọrọ Pasitọ Tunde Bakare bẹrẹ, eyi ni ọkunrin oloṣelu naa ko ṣe bọ sita wi nnkan kan.
Awọn kan ko tilẹ gba ọrọ ti Alukoro rẹ yii sọ, wọn ni irọ ti pọ ju lọdọ awọn oloṣelu, paapaa awọn ti wọn ba lorukọ ni Naijiria, bi kinni kan n ṣe wọn, wọn yoo ni ko si nnkan kan ni, nitori wọn ko ni i fẹ ki awọn araalu ati awọn alatako wọn mọ ohun to n lọ. Eyi ti tubọ jẹ kawọn eeyan maa wa ọna gbogbo lati ri awọn ti wọn mọ ti wọn si mọ Tinubu lati beere pe ṣe ko si nnkan kan lara olori ẹgbẹ APC naa, pe ṣe loootọ lo wa ni alaafia ara. Ohun to tubọ jẹ ki aya awọn eeyan ja ni pe awọn pupọ ni wọn mọ pe France ni Tinubu wa, eyi ti Alukoro rẹ n sọ pe ko si nibẹ, pe London lo wa bayii, wọn ni ko si idi ti ọkunrin naa fi le maa purọ, bi ko ba jẹ loootọ ni kinni kan n ṣe Jagaban, ti ko si sẹni to mọ bi kinni naa ṣe jẹ gan-an. Awọn ti wọn ko tilẹ ri ọkunrin yii, tabi mọ ẹni kan to mọ ọn naa ko dakẹ, pupọ ninu wọn n gbadura ni, pe Ọlọrun ma jẹ ki nnkan ṣe Tinubu o.
Awọn ti wọn n pariwo yii ko le ṣe ki wọn ma sare kiri nitori Tinubu, nitori lati oṣu to kọja lọ ni nnkan ti tubọ n le si i lori ọrọ Korona, paapaa laarin awọn olowo ati ọlọla, niṣe ni arun naa n mu wọn kiri, bo ba si ti mu olowo gidi tabi oloṣelu nla kan, ko ni i fi i silẹ bi ko ba pa a. Yatọ si awọn oloṣelu pataki bii Abba Kyari, Issa Funtua, Isiaka Abiọla Ajimọbi, Buruji Kaṣamu, Tunde Ibrahim, Adebayọ Ọṣinọwọ (Pepperito), ati awọn mi-in bẹẹ, ti aisan Korona yii ti mu ni ibẹrẹ ọdun, oṣu to kọja lọ yii ni kinni naa tun gba ọna mi-in yọ ni Naijiria, to si doju kọ awọn olowo, oloṣelu ati alagbara taara, to tun n pa wọn. Nigba ti awọn eeyan ro pe aisan naa ti lọ lo tun rọri pada, agbara to si gbe wa lasiko yii ju ti eyi to ti wa tẹlẹ lọ. Awọn ti awọn eeyan ko fọkan si rara lo n mu, bo si ti mu wọn ni yoo sọ wọn sọhun-un, nitori ko ni i fi wọn silẹ, afi to ba pa wọn.
Ni ibẹrẹ oṣu to kọja yii ni kinni naa kọ lu ọga ologun ọmọ ipinlẹ Kogi kan, John Olubunmi Irefin. Ki i ṣe pe aisan naa ba ọkunrin yii finra pupọ, nitori laarin ọjọ mẹta si mẹrin ti wọn ni kinni naa ti mu un naa lo ku, ọrọ si di ariwo nitori oun ati awọn olori awọn ṣọja ni wọn jọ n ṣepade pọ nibi to ti mu un. Mejọ Jẹnẹra ni Irefin ninu iṣẹ ṣọja, awọn ti wọn si jọ n ṣepade naa ki i ṣe oloye kekere ninu isẹ ologun, nitori olori awọn ṣọja pata, Ọgagun Agba Tukur Buratai naa wa laarin wọn. Kia ni gbogbo awọn ti wọn jẹ ọga ṣọja ti wọn wa nipade naa ti sare kuro nipade, ti awọn mi-in ko si jade sita fun odidi ọsẹ mẹta mi-in, nibi ti wọn ti n ṣe ayẹwo ara wọn, wọn n fẹẹ mọ boya awọn naa ti ni arun yii tabi wọn ko ni in. Gbogbo awọn ọmọọṣẹ wọn paapaa ni girigiri ọrọ naa mu, nitori ko sẹni kan to ro pe ara oun mọ.
Nibi ti wọn ti n ṣe bayii laarin ara wọn ni gudugbẹ ti ja, ti ariwo ta pe Olu Warri waja. Ohun to jẹ ki ọrọ naa la ariwo dani gan-an ni pe wọn ni ọba naa ati Ọgagun Irefin to ku ti jọ wa pọ fun ọjọ diẹ ko too di pe tọhun gbe arun Korona, to si gba ibẹ ku. Igbagbọ wọn ni pe arun Korona ti Olu Warri yii ko, lara Ọgagun Irefin ni, oun naa lo si ṣe iku pa a. Loootọ awọn ara aafin ati oloye ilu sare jade pe ko si ohun to jọ ọ, ọba awọn ko ku, o kan n ṣaarẹ lasan ni, sibẹ awọn ti wọn mọ bo ti n lọ ni bi wọn ti maa n ṣe bi awọn ọba alagbara ba ku niyẹn, wọn yoo pa oku rẹ mọ titi ti wọn yoo fi ṣe oro to yẹ ki wọn ṣe ni. Idi ni pe lati igba ti awọn oloye yii ti gbe e jade pe ọba awọn ko ti i ku o, ko sẹni to ri ọba naa nibi kan, bẹẹ ni ko si ti irinajo ti wọn lo ti lọọ gba itọju de, gbogbo eyi si ti le ni ọsẹ mẹta gbako.
Ọpọ awọn gomina ilẹ wa ni kinni naa ti mu lẹnu lọwọlọwọ yii, koda o ṣẹṣẹ fi Gomina Babajide Sanwo-Olu ti ilu Eko silẹ ni. Fun ọjọ mẹrinla tabi ju bẹẹ lọ ni Gomina Babajide Sanwo-Olu fi wa ninu ile, ti ko si jẹ ki ẹnikẹni sun mọ oun. Ile rẹ lo ti n ṣiṣẹ, ti awọn ti wọn n ba a ṣiṣẹ ko too di pe arun yii jade lara rẹ naa sare gba ile itọju lọ fun ayẹwo, wọn n fẹẹ mọ boya awọn ti ko o tabi awọn ko ti i ko o. Lẹyin ọjọ kẹrinla ni ọkunrin naa jade sita, to si ni ara oun ti gbadun, oun ko ni arun naa lara mọ. Nasir El-Rufai ti i ṣe gomina Kaduna naa ti tun ko o lẹẹkeji. Ṣe oun ti ko o ri, to si wa nile kanrin kese ko too pe arun naa lọ lara rẹ pata. Ṣugbọn nigba ti kinni naa tun de lẹẹkeji yii, El-Rufai ti ko o, o si ti jokoo sile lai jade, o tọju ara rẹ titi to fi gbadun lẹẹkeji yii, to si n ba iṣẹ rẹ lọ. Ọpọ awọn gomina ni kinni naa tun mu ti won ko pariwo rẹ sita.
Bi a ti n gbaradi lati mu ọdun tuntun yii, lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kejila to ṣẹṣẹ ko ẹru rẹ lọ yii, niṣe ni ariwo bẹ lojiji pe Ọjọgbọn kan ti wọn n pe ni Fẹmi Ọdẹkunle ti ku, ati pe Korona lo pa a lai ni iyemeji ninu. Fẹmi Ọdẹkunle ki i ṣe eeyan lasan, oun ni ọjọgbọn akọkọ ni Naijiria yii ninu imọ iwa ọdaran, ohun ti gbogbo aye fi maa n wa a kiri niyi. Bi a ti n wi yii, ọkan ninu awọn ti wọn wadii ohun to n fa iwa ọdaran fun ijọba yii ni. Ki o too de ipo tuntun to wa yii, ọpọ ijọba lo ti ba ṣiṣẹ, to si jẹ pe ko si ohun meji to n kọ wọn tabi to maa n ṣalaye ẹ, ti yoo si ṣiṣẹ lori rẹ fun wọn ju awọn ohun to maa n fa iwa ọdaran lawujọ lọ. Ni aye ijọba Abacha ni orukọ ọkunrin yii jade ju lọ, nitori nigba naa ni wọn mu un mọ awọn Ọgagun Ọladipọ Diya, ti wọn ni o wa lara awọn ti wọn fẹẹ fibọn gbajọba, tabi pe o mọ nipa ohun to ṣẹlẹ nigba naa gan-an.
Bẹẹ ohun to ṣẹlẹ ni pe Ọdẹkunle yii jẹ Oludamọran pataki fun Diya nigba naa, iṣẹ ijọba yii lo n ṣe. Nigba to ri i pe o waa sun kan Diya yii, awọn ti wọ mu wọn nigba naa ti ro pe ko si ohun ti Diya ṣe ti Ọdẹkunle ko ni i mọ, nigba ti ko si ti jade ko waa sọ ọrọ naa, a jẹ pe wọn jọ di i ni. Ohun to sọ ọkunrin naa di ero atimọle ree, to si tibẹ gba idajọ ẹwọn, to si wa nibẹ pẹ titi. Nigba ti Abacha ku lojiji ni wọn too fi i silẹ, to si ṣalaye ohun toju rẹ ri fun awọn ọmọ Naijiria gbogbo. Ṣugbọn bo ti pada de yii naa lo ti gbe iṣẹ rẹ pada, to si n ṣe e lọ, ko too waa di pe Korona ṣi i lọwọ iṣẹ naa ni ipari ọdun to kọja yii. Ọrọ iku rẹ mu ijaya dani, nitori ohun ti wọn n sọ ni pe bi iru iku yii ba le pa Ọdẹkunle, ẹni to ti ja oriṣiiriṣii ogun aye ti iku ko pa, to ba jẹ Korona lo waa mu un lọ, a jẹ pe Korona yii, ohun to yẹ ki eeyan sa fun ni. Awọn ti iku rẹ tilẹ ṣoju wọn gan-an ṣalaye nigba naa pe Korona naa fi oju rẹ ri nnkan ko too mu un lọ.
Eyi to waa pabambari ni ti iku to pa ọmọwe nla kan ni ijẹta ode yii, iyẹn lọjọ Aiku, ti i ṣe Sannde ọjọ kẹta, oṣu ki-in-ni, ọdun yii. Ọjọgbọn nla yii ki i ṣe ẹni ti awọn eeyan yoo ro iku si ni ọpọlọpọ ọdun, nitori ojulowo ọmọ Yoruba ni. Ọjọgbọn Oyewusi Ibidapọ-Obe ni, ẹni to ti figba kan jẹ olori ile-ẹkọ giga Yunifasiti Eko (UNILAG), to si ti di awọn ipo nla mu kaakiri origun mẹrin agbaye. Ko si a n fi ọrọ bọpo bọyọ ninu ẹ, kia lawọn ti wọn kede iku rẹ ti sọ pe arun Korona yii naa lo pa a, ati pe ki i ṣe pe o pẹ lori akete aisan to bẹẹ, kinni naa kọlu u laarin ọjọ mẹta pere siraawọn ni, o si ṣe bẹẹ mu un lọ. Iku rẹ ka ọpọlọpọ awọn eeyan lara, nitori ki i ṣe ẹni ti wọn ko mọ yikayika Naijiria ati ni ibi gbogbo ni Afrika, pẹlu awọn orilẹ-ede agbaye mi-in, nibi to ti fun wọn ni omi imọ mu. Ṣugbọn pẹlu gbogbo bẹẹ naa, ohun to fi pari rẹ ni ikede iku rẹ ni Sannde ijẹta, Korona naa lo si pa a.
Kinni naa di ijaya debi pe ọpọlọpọ awọn ijọba ni ipinlẹ gbogbo ni wọn ko jẹ ki awọn ọlọdun Keresi tabi ọdun nla ṣọdun naa lọdọ tiwọn. Kaluku lo fagile aisun ọdun yii, nitori wọn ni nibẹ ni ijo rẹpẹtẹ yoo ti waye, ti awọn eeyan yoo si lugbadi arun naa, ti yoo si tibẹ maa tan kaakiri. Awọn ọmọleewe paapaa ko ti i le wọle mọ nitori ijọba n sọ pe afi ko da awọn loju pe arun naa ti kasẹ nilẹ ki awọn too le ni ki awọn ọmọ ọlọmọ maa pada bọ nileewe, ko ma di pe wọn wọle ti kinni naa a gbẹyin yọ, ti yoo si bẹrẹ si i pa awọn ọmọ ọlọmọ. Bo tilẹ jẹ pe minisita eto iroyin fun ijọba apapọ, Alaaji Lai Muhammed ti kede pe ko ni i si ofin konilegbele mọ lori ọrọ Korona ẹlẹẹkeji yii, sibẹ, awọn ijọba mi-in ko faaye gba awọn oṣiṣẹ kan lati maa lọ sibi iṣẹ, awọn ọga nikan lo n lọ. Wọn ni bi gbogbo oṣiṣẹ ba n lọ lojoojumọ, arun naa le gbilẹ ju ohun ti apa yoo ka lọ.
Ohun to ya awọn eeyan lẹnu ni bi arun naa ṣe tun fo gija lojiji, to si tun gbilẹ kaakiri. Wọn ni arun Korona ti lọ, awọn si ti ro pe ko tun ni i pada wa mọ, eyi to waa de to tun n pa awọn eeyan loriṣiiriṣii yii, ọrọ naa ko fẹẹ ye awọn mọ. Awọn ti wọn mọ ohun to ṣẹlẹ gan-an lo ṣalaye ọrọ, pe arun naa ko ba ti de Afrika, tabi Naijiria mọ, bi ki i ba ṣe pe awọn ijọba wa sare ṣi ẹnubode ilẹ wa, ti wọn si tun ni ki awọn ẹronpileeni maa fo lọ, ki wọn maa fo bọ bi wọn ba ti fẹ. Wọn ni ohun to fa a ree, nitori nigba ti arun ti gbilẹ, to tun bẹ lẹẹkeji si aarin awọn orilẹ-ede eebo yii, bi wọn ti n ko o lọhun-un naa ni wọn n ko o waa ran awọn eeyan to wa nile, nitori awọn ti wọn n rin irinajo si ilu oyinbo, tabi awọn ti wọn n pada bọ wa sile, pọ gan-an ni Naijiria, awọn yii lo si n ko o ran awọn ọmọ Naijiria ti ko jade nile, awọn ti wọn ko tilẹ mọ kinni kan.
Bi a ti ṣe n wi yii, ohun ti ko ṣẹlẹ ri ṣẹlẹ ni Amẹrika lọsẹ to kọja. Lọjọ kan ṣoṣo, awọn ti wọn ko kinni naa le ni ẹgbẹrun lọna igba (200,000), iru rẹ ko ṣẹlẹ nibi kan ri, afi ilẹ Amẹrika yii nikan. Ọrọ naa le lọhun-un debi pe awọn ti wọn ti ko Korona nibẹ le ni miliọnu mọkanlelogun, awọn to si ti ku jẹ ẹgbẹrun lọna ọtalelọọọdunrun ati mejidinlogọrin (360,078). Awọn ti wọn wa ni ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun ni Amẹrika bayii ti le ni miliọnu mẹjọ eeyan, ẹsun ti wọn tilẹ si fi n kan olori ijọba ibẹ bayii, Donald Trump ni pe ko ba awọn da si kinni kan mọ, o kan n fẹ kawọn ara Amẹrika maa ku lọ lọwọ Korona ni. Trump naa ko jẹ ki ọrọ naa tutu, o ni asọdun awọn eeyan pọ ju lori ọrọ naa, ki wọn ma fi wahala pa oun, ki wọn jẹ ki ẹni to ba fẹẹ ku, ku, ki awọn si mọ iye eeyan to ba ṣẹ ku, tori arun naa ki i ṣe ti Amẹrika, awọn China lo ko o wa sigboro.
Ṣugbọn ki i ṣe Amẹrika nikan ni Korona ti sọ iku di meji eepinni bẹẹ, ibi to bọ si lara wọn ni Brazil paapaa ko daa. Bi a ti n wi yii, lọdọ tiwọn lọhun-un ẹgbẹrun lọna mẹrindinnigba ati mejidinlogun (196,018) lawọn ti Korona ti lu pa nibẹ, bẹẹ ni awọn bii miliọnu kan din diẹ wa lẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun. Orilẹ-ede India lo tẹ le wọn, bii miliọnu mẹwaa lo ti ko o, awọn ẹgbẹrun lọna aadọjọ din diẹ (149,686) lo ti ta teru nipaa lọwọ arun yii, bii ojilenigba ẹgbẹrun si wa lori boya-wọn-a-ku, boya-won-a-ye. Awọn ara Mexico paapaa nipin ninu iku ajọku yii, nitori ẹgbẹrun lọna aadoje din mẹrin (126,000) lo ti ba a lọ, bo tilẹ jẹ pe awọn to mu lọhun-un ko ju miliọnu kan ataabọ lọ. Ẹgbẹrun lọna okoolenigba ati marun-un (225,000) lọwọ kinni naa ti rin mọlẹ pata, to jẹ pe ko sẹni to le sọ boya kinni naa ko ni i di ọlọjọ fun wọn.
O ti di ẹẹmeji bayii ti wọn ti ṣe ofin konilegbele ni Britain, nitori nigba ti kinni yii ti tun yọju lẹẹkeji ni wọn ti kọkọ sare ṣe ofin, wọn ko jẹ ki ẹni kan jade lọ. Nigba ti wọn ri i pe o tun rọlẹ diẹ, wọn ni ki awọn eeyan bẹrẹ si i jade, ṣugbọn lẹẹkan naa ni wọn tun tilẹkun, wọn ni awọn ko fẹ ero, bẹẹ lawọn ko fẹ ẹni ti yoo maa jade, ki kaluku wọn gbele wọn ni. Wọn ko si le ṣe ki wọn ma tun sare gbe ofin jade bẹẹ, nitori awọn ti wọn ti ku nibẹ ti le ni ẹgbẹrun lọna marundinlọgọrin (75,000), bẹẹ ni iku naa ko si duro, o n le si i ni, iyẹn ni wọn ṣe sare gbe ofin konilegbele jade. Iye awọn ti wọn ti ku ni ilu Italy naa niyi, bo tilẹ jẹ pe tiwọn le ọgbọn lọọọdunrun (75,330). N lawọn naa ba yaa sare ṣe ofin tuntun pe ko ni i si aaye arinkiri fẹnikan mọ, wọn ni ọrọ yii ti kọja a-n-fẹkọ-tanna fun ara ẹni jẹ. Oku ku ni France, o ku ni Spain ati ilẹ Yuroopu yikayika, Korana ẹlẹẹkeji ni gbogbo wọn si n pariwo.
Nitori pe kinni naa ti mu wọn kaakiri bayii ni awọn ilu oyinbo wọnyi, kia lo ti ran kari Naijiria naa, to si di ohun to n mu awọn tewetagba, to jẹ awọn arinrinajo lo n ko wọn wa. Ọrọ naa ti dohun ti awọn kan fi n jẹun, nitori bi wọn ba ti ilu oyinbo de, kaka ki wọn lọ si aaye-iyara-ẹni-sọtọ, tabi ki wọn pada lọọ ṣe tẹẹsi, wọn yoo kan fun awọn ti wọn wa nibẹ lowo ni, wọn yoo si gba sabukeeti pe ṣaka lara awọn da. Bẹẹ wọn ko ṣe tẹẹsi, wọn ko si yẹ ara wọn wo boya Korana mu wọn tabi ko mu wọn. Ohun to jẹ ki arun yii gbilẹ rẹpẹtẹ lojiji ree, nitori awọn ti wọn n de lati ilu oyinbo ko ṣe tẹẹsi, bẹẹ ni wọn ko lo oogun, wọn kan dara pọ mọ awọn araalu ti wọn ti ri ara wọn tipẹ, ti wọn yoo si maa lọ mọ ara wọn kaakiri ni. Ohun to fa a tijọba fi fofin de awọn arinrinajo kan ti wọn de, ti wọn ko lọ sibi ayẹwo ree, ati awọn ti wọn de ti wọn ko pada lọ mọ. Ijọba ni fun oṣu mẹfa, ko sẹni ti yoo jade kuro ni Naijiria ninu wọn.
Ijọba gba nọmba pasipọọtu wọn silẹ ni, wọn si ti fun awọn ẹṣọ oju ọna yii, debi pe ko ni i sẹni ti yoo le jade kuro ni ẹnubode Naijiria ninu wọn afi ti ko ba lo pasipọọtu to wa lọwọ rẹ naa. Ṣugbọn arun naa ko jọ pe yoo tete lọ bọrọ nitori o ti wa niluu, o si n mu awon eeyan lojoojumo si i ni. Eyi ni ijọba ṣe n pariwo pe eni to ba wẹ ni yoo jare ọbun, ẹni to ba tọju ara rẹ, ti ko si ṣere lọ si ibi ti awọn ero pọ si lo le yọ ninu rẹ. Awọn araalu kan ko tilẹ gba pe Korona lo n ṣiṣẹ eyikeyii, tabi pe arun to le mu awọn ni. Ohun ti wọn n sọ ni pe arun awọn olowo ni, awọn olowo ti wọn ti fẹẹ ku tẹlẹ, iku to ti wa lara wọn lo n pa wọn, ki i ṣe Korona kankan. Awọn mi-in to si mọ pe Korona wa, sọ pe ki i ṣe arun awọn akuṣẹẹ, arun awọn olowo ni, olowo lo n mu, awọn naa ni yoo si maa mu lọ. Ṣugbọn Korona yii ko mọ olowo, ko mọ mẹkunnu, ẹni to ba ri lo n mu, ki alara ṣọra rẹ gidi ni o.