Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Afi ki gbogbo mọlẹbi atawọn ti wọn ba fẹran ọkunrin kan ti wọn n pe ni Samuel Alade-Ẹmin, niluu Akurẹ, nipinlẹ Ondo, wọle adura gidigidi fun un, nitori ko ti i ṣeni to le sọ ohun ti yoo ṣẹlẹ si i pẹlu ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan an. Ọkan ninu awọn ọmọ ijọ rẹ ni won lo fun ni majele jẹ, ti iyẹn si gbabẹ ku. Ọrọ naa si ti de kootu bayii.
ALAROYE gbọ pe iṣẹlẹ yii waye labule kan ti wọn n pe ni Alagbado, Ọrẹ, n’ijọba ibilẹ Odigbo, laarin ọjọ kejilelogun si ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹjọ ọdun ta a wa yii.
Adajọ kootu Majisireeti kin-in-ni to wa l’Oke-Ẹda, niluu Akurẹ, Onidaajọ Musa Al-Yunnus, si ti paṣẹ pe ki wọn lọọ fi wolii Samuel Alade-Ẹmin, pamọ sọgba ẹwọn lori ẹsun pe o ṣeku pa ọkan ninu awọn ọmọ ijọ rẹ, Ọlaṣupọ Abiọna, nipa fifun un ni majele jẹ.
Agbefọba, Nelson Akintimẹhin, ṣalaye lasiko ti wolii ẹni ọdun marundinlaaadọta naa fara han nile-ẹjọ pe ọmọ ẹni to jẹ iya-ijọ rẹ ni oloogbe ọhun.
O ni lojiji ni Abiọna deedee di awati, tawọn ẹbi rẹ si wa a titi, ti wọn ko mọ ibi to wọlẹ si. Ṣugbọn lẹyin ọpọlọpọ wahala ni wọn pada ri ọmọkunrin naa lakata Wolii Samuel, iyẹn lẹyin odidi ọjọ meje ti wọn ti n wa a.
Agbefọba ni niṣe ni wọn sare gbe ọmọkunrin ọhun lọ sọsibitu ni kete ti wọn ri i latari majele ti wọn ni wolii yii ti fun un jẹ, eyi to mu ko maa pọ ẹjẹ lẹnu. O ni ileewosan naa lo pada ku si lẹyin bii ọjọ mẹwaa to ti n gba itọju.
Ẹsun meji ti wọn ka si ojisẹ Ọlọrun naa lẹsẹ ni gbigbe ọmọkunrin naa pamọ, eyi to lodi si ifẹ inu rẹ ati fifun un ni majele jẹ, eyi to mu ko maa pọ ẹjẹ lẹnu, to si pada ja si iku fun un.
Ẹsun mejeeji yii ni wọn lo ta ko abala ọta-le-lọọọdunrun-le-marun-un (365) ati okoo-le-nirinwo-din mẹrin (316) ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2016.
Akintimẹhin sọ ninu ẹbẹ rẹ pe oun fẹ ki kootu paṣẹ pe ki wọn fi olujẹjọ naa pamọ sọgba ẹwọn titi ti awọn yoo fi ri imọran gba lati ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran.
Nigba to n sọ iha tirẹ lori ẹsun ti wọn fi kan an, Wolii Samuel ni funfun balau lọwọ oun mọ lori awọn ẹsun naa. O ni loootọ ni Abiọna n gba itọju ninu sọọsi oun ko too deedee di awati.
Ni kete to tun fẹsẹ ara rẹ rin pada wa loun ni ki iyawo oun tete pe iya rẹ lati fi to o leti. O ni lẹyin ti iya rẹ de to si foju ara rẹ ri ọmọ rẹ pẹlu ipo to wa ni awọn ṣẹṣẹ ṣeto ati gbe e lọ si ile-iwosan, nibi to pada ku si.
Agbẹjọro olujẹjọ, Amofin A. Motunrayọ, bẹbẹ fun beeli onibaara rẹ nitori pe ẹtọ olujẹjọ ni beeli gbigba jẹ labẹ ofin.
Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ, Onidaajọ Musa Al-Yunnus, ni ki Wolii Samuel ṣi wa lọgba ẹwọn titi di ọjọ kẹsan-an, oṣu Keji, ọdun to n bọ.