Faith Adebọla
Nnkan ko fara rọ rara lasiko yii nipinlẹ Imo, pẹlu bawọn agbebọn kan ṣe ya bo Okigwe South Eria Kọmandi ipinlẹ naa to wa nijọba ibilẹ Ehime Mbano, lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ti wọn yinbọn pa ọlọpaa marun-un, wọn ṣe ọpọ eeyan leṣe, wọn sì dana sun teṣan naa.
Yatọ sawọn ọlọpaa ti wọn pa, awọn janduku naa tun jalẹkun awọn ahaamọ ọlọpaa to wa níbẹ, wọn tú gbogbo awọn to wa lahaamọ sílẹ, bẹẹ ni wọn ko awọn ibọn ati ọta ibọn ti wọn rí, titi kan awọn dukia olowo iyebiye mi-in.
ALAROYE gbọ pe awọn agbebọn naa pọ bii baba eṣua, wọn ni bí wọn ṣe yọ sileeṣẹ ọlọpaa naa tijatija ni wọn ti dana ibọn ya awọn ọlọpaa marun-un ti wọn ba niwaju ileeṣẹ ohun, wọn pa wọn nifọnna-fọnṣu.
Iro ibọn to n dun lakọlakọ lo mu kawọn agbofinro to ku níbẹ gbọna ẹyin sa lọ, awọn aladuugbo tó n kọja lọ kọja bọ si ni lati sa asala fẹmii wọn.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Imo, Ọgbẹni Orlando Ikeokwu, fìdí iṣẹlẹ yìí mulẹ, o sọ pe ọlọpaa marun-un lawọn ṣi ṣiro pe wọn ba iṣẹlẹ naa lọ.
Ikeokwu ni awọn ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa ti n fori kori lati gbe igbesẹ to yẹ lori iṣẹlẹ ibanujẹ yii.