Wọn pa ‘Star boy’, gbajumọ ọmọ ẹgbẹ okunkun n’Ilọrin

Stephen Ajagbe, Ilorin

Awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun ti ṣeku pa ọkan lara wọn tawọn eeyan mọ si Star boy, lagbegbe Olumawu, niluu Ilọrin.

ALAROYE gbọ pe laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, lawọn araadugbo atawọn to n kọja niyana Olumawu, lọna Police Link road, ṣadeede ri agbari ọdọmọkunrin naa nibi ti wọn gbe e ju si.

Iwadii fi han pe lẹyin tawọn to ṣeku pa a ge ori rẹ, wọn gbe iyooku ara rẹ ju sinu igbo to wa nitosi ibi ti wọn gbe ori rẹ si.

Ikorita Olumawu gan-an ni wọn patẹ agbari Star Boy si fun gbogbo awọn to ba n kọja lati fi ṣeran wo.

Iṣẹlẹ naa ti sọ awọn to n gbe agbegbe ọhun sinu ibẹru, idi ni pe wọn n ro o pe o ṣee ṣe kawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun tun fija pẹẹta.

Wọn ke si awọn agbofinro lati gbe igbesẹ lọna ati fopin si bawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ṣe n pa ara wọn nipakupa.

Leave a Reply