Stephen Ajagbe, Ilorin
Kayeefi lo ṣi n jẹ fawọn eeyan, paapaa awọn to ni ṣọọbu lagbegbe Post Office, niluu Ilọrin, nitori bi ajọ aabo ẹni laabo ilu, NSCDC, ṣe ri agbari eeyan lori afara to wa nibẹ laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.
Agbari ọhun to jọ ti ọdọmọde ni awọn oṣiṣẹ NSCDC ri ninu lailọọnu dudu, ti wọn si tun gbe e ju sẹgbẹẹ titi lori afara ọhun.
Titi di bi a ti ṣe n sọ yii, ko ti i sẹni to mọ bi kinni ọhun ṣe debẹ, ṣugbọn awọn eeyan ni awọn to fẹẹ ṣoogun owo tabi to n ta ẹya ara eeyan lo maa gbe e ju sibẹ.
Ju gbogbo ẹ lọ, ileeṣẹ NSCDC ti n ṣewadi lori ẹ, igbagbọ si wa pe wọn yoo ṣawari awọn to huwa ọdaran naa laipẹ