Faith Adebọla, Eko
Bi adiyẹ ba da mi loogun nu, ma a si fọ ọ lẹyin lọrọ da bayii pẹlu bawọn olooṣa ṣe lọọ wa abujo ati epe kabiti kabiti le awọn to ji ọpa aṣẹ ọba Eko gbe sa lọ, ti wọn si kọ lati da a pada.
Fidio kan to n ja ranyin-ranyin lori atẹ ayelujara bayii ni awọn olooṣa ti wọn san aṣọ funfun mọdii naa, ti wọn gbe ẹbọ kalẹ ni ojubọ Eṣu, ti wọn si bẹrẹ si i ṣepe ati ayajọ lede Yoruba fawọn ti wọn ṣe aafin Elekoo ilu Eko, Ọba Riliwanu Akiolu, baṣubaṣu l’Ọjọruu, Wẹsidee, to kọja yii.
Tẹ o ba gbagbe, lasiko ti rogbodiyan n lọ lọwọ nipinlẹ Eko latari bawọn janduku tinu n bi ṣe n sọ ina si awọn dukia ti wọn foju sun ni awọn kan ya wọ aafin ọba alaye naa, ti wọn si gbe ọpa aṣẹ, bata ati posi funfun kan sa lọ. Ori lo ko Ọba Akiolu yọ lọjọ naa, awọn agbofinro ni wọn fi ẹyin pọn ọn jade tọwọ awọn janduku naa ko fi to o.
Ko ti i sẹni to foju kan ọpa aṣẹ naa pẹlu gbogbo arọwa ti awọn mọlẹbi kabiyesi atawọn ọtọkulu lawujọ ti ṣe. Eyi lo mu kawọn olooṣa ohun gbe ọrọ naa gba ọna iṣẹmbaye, ti wọn fi n bẹgi fawọn to huwa abuku si ori ade ọhun.