Faith Adebola
Bi ko ba jẹ awọn panapana ti wọn tete debẹ ni, afaimọ ni teṣan awọn ọlọpaa ni Ojodu ko ni i jona gburugburu. Ṣugbọn awọn panapana tete debẹ, wọn wa nibẹ bi a ti n ko iroyin yii jọ, agọ ọlọpaa naa ko si jona tan. Sibẹ, ẹgbẹ kan jona, mọto mẹfa si ba ọrọ naa lọ ninu ọgba wọn nibẹ.
Lati ana, Ọjoruu, Wẹsidee, ni wọn ti n dooyi ka adugbo naa, ti wọn n fẹẹ sun teṣan yii, ṣugbọn ti awọn ọlọpaa ibẹ ko faaye gba wọn lati le ṣe e. Ṣugbọn ni ti oni yi, apa ko ka wọn mọ, wọn si kọ lu teṣan naa, ki wọn to sọna si i.
Ki i ṣe teṣan yii nikan ni awọn janduku yii kọ lu, wọn de awọn ṣọọbu kan nitosi agọ ọlọpaa naa, ti wọn si sun wọn, ti wọn si ja wọn lole, ki wọn too ri wọn le lọ. Awọn ọlọpaa ti pọ si i nibẹ, ọrọ naa ko si ti i yanju tan patapata.