Wọn ti gbe oku awọn ṣọja to padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ ofurufu lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, yii wa siluu Abuja.
Isin n lọ lọwọ nilana Musulumi fun awọn to jẹ Musulumi ninu wọn, nigba ti isin tawọn Onigbagbọ naa n lọ lọwọ lati bu eyẹ ikẹyin fun awọn akikanju to ku ọhun.
Itẹkuu awọn ologun to wa niluu Abuja ni wọn n ṣeto si lati sin wọn si.