Wọn ti ja mẹwaa ninu awọn oludije ipo aarẹ ẹgbẹ APC

Monisọla Saka
Igbimọ to n ṣewadii awọn oludije dupo aarẹ lẹgbẹ APC, eyi ti Oloye John Odigie Oyegun jẹ olori fun ti yọ awọn mẹwaa danu ninu awọn mẹtalelogun to n dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC danu.
Oyegun sọ eleyii di mimọ nigba to gbe abọ iwadii ikọ igbimọ ẹlẹni meje rẹ siwaju alaga apapọ ẹgbẹ ọhun, Sẹnetọ Abdullahi Adamu, nile ẹgbẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii.
Iroyin lẹkun-un-rẹrẹ nipa awọn ti wọn yọ atawọn ti wọn yege, ti wọn yoo si lanfaani lati kopa ninu ibo abẹle wọn lọjọ Aje, Mọnde ni ẹgbẹ naa ko ti i fi lede.
Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa yii ni eto idibo abẹle ẹgbẹ naa yoo waye.

Leave a Reply