Wọn ti mu awọn eleyii ni Kwara, ibọn ni wọn fi maa n ja ọkada araalu gba

 Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọwọ palaba awọn ọdaran mẹrin kan, Jibril Sani, Abdullahi Sani, Mohammed Suleiman ati Abubakar Shede, ti wọn maa n fibọn ja ọkada gba lọwọ awọn araalu ti segi lagbegbe Bàbáńlá, nipinlẹ Kwara, lẹyin ti wọn ja ọkada gba lọwọ olugbe Amọ́yọ̀, niluu Ilọrin lọwọ tẹ wọn.

Kọmiṣanna ọlọpaa ni Kwara, CP Victor Ọlaiya, ṣalaye lasiko to n ṣẹ afihan wọn fawọn oniroyin pe Ọgbẹni Jimoh Taiye, to n gbe ni agbegbe Amọ́yọ̀, niluu Ilọrin, lo mu ẹsun wa si olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa pe lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keji, ọdun 2024 yii, ni awọn janduku kan ja ọkada Bajaj to ni nọmba EDE 340QB, gba pẹlu ibọn lọwọ oun lasiko toun n rin irin-ajo lẹnu bode Kwara si ipinlẹ Kogi. O ṣalaye pe lẹyin ti wọn gba ọkada Bajaj ọhun tan, wọn tun gba foonu ilewọ meji, baagi kan ti owo, ATM kaadi ati awọn dukia miiran wa, ti gbogbo owo rẹ jẹ miliọnu kan Naira (1m), ti wọn si gbe gbogbo rẹ sa lọ.

Ọlaiya sọ pe nigba ti iwadii bẹrẹ ni ọwọ tẹ Jibril Sani, to n gbe niluu Bàbáńlá, ni Guusu Kwara, ko too di pe wọn ri awọn mẹta yooku mu, ti gbogbo awọn afurasi ọhun si jẹ olugbe ilu Bàbáńlá. Bẹẹ ni wọn ti ri ọkada Bajaj ti wọn ji gba pada lọwọ wọn.

Kọmisanna tẹsiwaju pe lẹyin ẹkunrẹrẹ iwadii, awọn afurasi naa yoo foju balẹ-ẹjọ.

O ni, ileeṣẹ ọlọpaa ko ni i kaaarẹ ọkan, yoo maa tẹsiwaju ninu ilakaka wọn lati ri i pe iwa ọdaran di ohun igbagbe nipinlẹ Kwara. O waa gba awọn ọdaran nimọran pe ki wọn tete ko aasa wọn kuro nipinlẹ naa, nitori pe ko sibi ti wọn fẹẹ fara pamọ si ti ọwọ ofin ko ni i tẹ wọn.

Bakan naa lo gboriyin fawọn ọtẹlẹmuyẹ ti wọn lo ọgbọn inu ati oye ikun, ti wọn fi ri awọn afurasi ọdaran naa mu, ti wọn si tun ri dukia ti wọn ji ko gba pada lọwọ wọn.

 

Leave a Reply