Ibrahim du ọlọkada lọrun, lo ba ji ọkada ẹ gbe sa lọ

Adewale Adeoye

Nitori ẹsun pe o ji ọkada araalu kan gbe lẹyin to du onitọhun lọrun laipẹ yii, ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Karu, nijọba ibilẹ Karu, nipinlẹ Nasarawa, ti mu gende-kunrin kan,  Ibrahim Isiaka, ju sahaamọ, o si ti n ṣalaye ohun to mọ nipa iwa ti ko bofin mu to hu naa.

ALAROYE gbọ pe ọsẹ to kọja yii ni Ibrahim pe ọlọkada kan pe ko waa gbe oun lọọ sagbegbe Bigmali, loju ọna marosẹ Jankanwa, niluu Masaka, nipinlẹ Nasarawa. Lasiko ti ọlọkada ọhun n gbe e lọ lo ba yọ ọbẹ aṣooro kan jade, o du ọlọkada ọhun lọrun, lo ba ji ọkada rẹ gbe sa lọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, D.S.P Rahman Nansel, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ pe gbara tawọn ọlọpaa agbegbe naa ti gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun lawọn ti bẹrẹ si i ṣewadii, tọwọ si tẹ afurasi ọdaran ọhun laipẹ yii nibi to sapamọ si lagbegbe Masaka.

Alukoro ni ileewosan ijọba to wa lagbegbe naa tawọn gbe ọlọkada ọhun lọ lo ti n gba itọju bayii. Wọn ni awọn maa foju Ibrahim bale-ẹjọ laipẹ rara.

 

Leave a Reply