Ọlawale Ajao, Ibadan
Lẹyin bii oṣu kan ti wọn yinbọn pa Olori-Ọdọ lagbegbe Akinyẹle, n’Ibadan, ọwọ ọlọpaa ti tẹ awọn Fulani darandaran to huwa ọdaran naa.
Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ keji, oṣu kẹjọ, ọdun 2021 yii, ni wọn ṣafihan awọn afurasi apaayan naa ti wọn n jẹ Usman Mohammed, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, ati Umaru Mohammed toun jẹ ẹni ọdun mẹrindinlogun.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ijinigbe ni wọn fi bẹrẹ ipaniyan ọhun pẹlu bi wọn ṣe tan awọn ọmọ Yoruba kan lọ sinu igbo, ti wọn si ji wọn gbe. Awọn ọdọ agbegbe ọhun to tun fi ara wọn ji lati gba awọn to wa ni igbekun wọn silẹ lawọn ọdaju eeyan yii yinbọn pa ọga wọn ti wọn n pe l’Olori-Ọdọ.
Nigba to n ṣafihan awọn afurasi ọdaran naa, Ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Ngozi Onadeko, sọ pe eyi to n jẹ Umaru Muhammed ninu awọn Fulani wọnyi lo pe ọmọ Yoruba kan to n jẹ Taofeek pe maaluu to fẹẹ ra lọwọ oun ti wa nilẹ, ko tete maa bọ waa ba oun ni Kaara l’Akinyẹle lati waa gbe e.
O ni, “Bi Taofeek ṣe n gba ipe ọhun tan loun pẹlu aburo ẹ to n jẹ Yusuf Taiwo gun ọkada lọọ pade ọkunrin onimaalu naa laimọ pe iyẹn ti ṣeto awọn to maa ji wọn gbe soju ọna ibi ti wọn maa gba kọja lọ si Aba Onidundu ti wọn ni maaluu ọhun wa gan-an.
“Bi wọn ṣe de oju-ọlọmọ-o-to-o lawọn ajinigbe naa yọ si wọn tibọntibọn, ti wọn si ji Taiwo gbe nigba ti Ọlaide ribi ba sa mọ wọn lọwọ.
“Bi wọn ṣe fiṣẹlẹ yii to wa leti lawọn eeyan mi to n gbogun ti ijinigbe (Anti Kidnapping Squard, AKA) ti ya bo inu igbo gbogbo to wa lagbegbe yẹn, ti wọn si fin awọn afurasi ọdaran naa jade nibuba wọn.
“Bẹẹ la ri ẹni to wa ni igbekun wọn tu silẹ. Ibọn awọn afurasi ajinigbebyen ti ba a n’itan, nibi ti wọn ti n gbiyanju lati gbe e lọjọsi.
“Ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe bi awọn afurasi ọdaran yii ṣe n sa lọ ki awọn olopaa ma baa ri wọn mu, wọn pade awọn ọdọ adugbo yẹn kan loju ọna, wọn si yinbọn pa ọkan ninu wọn ti wọn n pe ni Olori-Ọdọ.
“Ninu itẹsiwaju iwadii ta a ṣe lori iṣẹlẹ bayii la ti ri Usman ati Umaru mu. Iwadii ṣi n lọ lọwọ lati ri awọn yooku wọn ti wọn jọ lẹdi àpò pọ lati huwa ọdaran yẹn mu.”
Eyi to n jẹ Umaru Muhammed ninu awọn Fulani naa sọ pe loootọ lawọn tan Taiwo ati Ọlaide lọ sọdọ awọn ajinigbe ki awọn le rowo gba lọwọ awọn ẹbi wọn leyin ti awọn ba ji wọn gbe tan. Ṣugbọn awọn ọdọ kan di awọn lọwọ, wọnyi ko jẹ ki awọn fara balẹ ṣiṣẹ naa plu bi wọn ṣe wa awọn wa sinu igbo. Eyi lo si mu ki awọn yinbọn fun wọn, ti ọkan ninu wọn fi jẹ Ọlọrun nipe.