Wọn ti mu Bethel, ayederu agunbanirọ to rapala wọ ipagọ wọn

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Nasarawa, ti mu ayederu agunbanirọ kan, Ọgbẹni Ogeh Bethel Chibuife, to si n ran wọn lọwọ ninu iwadii wọn lori bo ṣe pe ara ẹ ni ohun ti ko jẹ.

ALAROYE gbọ pe ọwo palaba Bethel to jẹ ayederu agunbanirọ naa segi nigba ti ọmọkunrin yii gba ipagọ awọn agunbanirọ kan to wa lagbegbe Magaji Dan Yumusa, niluu Kẹffi, nipinlẹ Nasarawa, lọ, to si ṣe bii pe ojulowo agunbanirọ loun naa fawọn ti wọn wa nibẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, DSP Ramhan Nansel, ni iwadii awọn pada fidi ẹ mulẹ pe akẹkọọ Fasiti ipinlẹ Ebonyi ni Bethel, to si yẹ ko ti kẹkọọ jade lọdun 2022, ṣugbọn nitori to n fidi-rẹmi nibi awọn idanwo ileewe naa lo fi dọgbọn lọọ wọ aṣọ agunbanirọ, ki awọn mọlẹbi rẹ le mọ pe o ti kẹkọọ jade.

Alukoro ni loju-ẹsẹ lawọn ti fọwọ ofin mu afurasi ọdaran yii, o si ti jẹwọ pe loootọ loun lọ si ọja lati lọọ ra aṣọ agunbanirọ ati awọn eroja miiran, toun si fọgbọn wọ ipagọ wọn k’oun le ya foto, ki awọn obi oun le ro pe oun ti kẹkọọ jade.

Leave a Reply