Wọn ti mu lọọya to lu onikẹkẹ Maruwa loogun  to fi ku n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa, ẹka ti ipinlẹ Kwara, ti tẹ Kayode Oluwatobi, lọọya to lu onikẹkẹ Maruwa kan,  Kọla Adeyẹmi, loogun to fi ku lagbegbe Garin Alimi, Ilọrin, nipinlẹ Kwara, lọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ naa, Ọkasanmi Ajayi, sọ ninu atẹjade to fi sita lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, pe ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni igbakeji alaga ẹgbẹ onikẹkẹ Maruwa,  ẹka ti Gari- Alimi/Asa Dam, Ganiyu Adebayo, mu ẹsun lọ si agọ ọlọpaa to wa ni Budo Nuhu, lagbegbe naa, pe lọọya kan ti lu onikẹkẹ Maruwa ọhun, Kola Adeyemi, to n gbe ni agbegbe  Boluwaji, ni Egbejila, Ilọrin, loogun, to si gbẹmii mi.

Ọkasanmi tẹsiwaju pe mọto ayọkẹlẹ Họnda alawọ dudu to ni nọmba iforukọsilẹ BX 954 AJL, ni lọọya naa n wa lọ ko too di pe ọnikẹkẹ Maruwa kọlu u lẹyin, ti pọnta rẹ to to ẹgbẹrun meji aabọ naira niye si fọ. Eyi lo fa ede aiyede laarin awọn mejeeji nigba ti onikẹkẹ sọ pe ẹgbẹrun meji naira pere ni oun yoo san, ni lọọya ba lu u loogun, lo ba ku patapata.

Ni bayii ọwọ ti tẹ lọọya naa, o si ti wa ni galagala ọlọpaa, wọn si lawọn yoo foju ẹ ba ile-ẹjọ laipẹ.

Leave a Reply