Wọn ti mu obinrin yii, owo ẹru lo n fawọn ọmọ ọlọmọ ṣe

Monisọla Saka

Ọwọ awọn ọmọ ogun ilẹ wa, Nigerian Army, ti tẹ obinrin ogbologboo afọmọṣowo-ẹru kan, Arabinrin Olushọla Areke, to fẹẹ ta ọmọ ti wọn fi si ikawọ ẹ si orilẹ-ede mi-in nipinlẹ Eko. Ninu atẹjade ti Agbẹnusọ ileeṣẹ ologun, Ọlabisi Ayẹni, fi sita lọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni wọn ti sọ ọ di mimọ pe ọwọ awọn ti tẹ obinrin naa.

Atẹjade naa ni, “Ikọ 65 Battalion Nigerian Army, to wa labẹ ẹka 81 Division, ti mu afọmọṣowo-ẹru kan mu nipinlẹ Eko. Olobo to ta wa lo jẹ ko rọrun fun wa lati ri Arabinrin Olushọla Areke mu lori ẹsun to ni i ṣe pẹlu jiji ọmọ gbe lati ta wọn s’Oke- Okun.

” Ẹsun pe afurasi ji Fayọkẹ Kunle, obinrin ẹni ọdun mejilelogun (22), to jẹ ọmọ bibi inu Arabinrin Aina Kunle ni a fi wa a kan. Alaye ti iya ọmọ yii ṣe ni pe oun loun fa ọmọ oun le afurasi yii lọwọ lẹyin to ṣeleri lati wa iṣẹ fun un l’Oshodi, nipinlẹ Eko.

“Amọ to jẹ dipo ko mu ọmọ lọ sibi iṣẹ to sọ ni Oshodi, Kano, nilẹ Hausa lọhun-un, ni wọn gbe ọmọbinrin yii lọ, nibẹ lọmọ naa ti feti kọ ọ pe awọn toun de si lọdọ n gbe oun lọ si orilẹ-ede Libya, nibi ti wọn yoo ti maa fi ṣiṣẹ ẹru.

Pẹlu ọgbọn ni ọmọ yii fi sa mọ awọn to ji i gbe lowo, to si dari pada sile lọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii.

“Ni kete ti ọrọ yii de etiigbọ wa lawọn ikọ wa pe Arabinrin Areke gẹgẹ bii onibaara to ni ọmọ to fẹẹ maa ta fun un, ọgbọn ni wọn si fi mu un nibi ti wọn jọ fẹnu ko si pe ki awọn ti pade lati bẹrẹ ajọṣe òwò naa”.

Wọn ni awọn ti taari ọmọbinrin ti ori ko yọ yii ati afurasi lọ si teṣan ọlọpaa Ajah, nipinlẹ Eko, fun iwadii to peye”.

Leave a Reply