Wọn ti mu Peter atawọn to ran pe ki wọn lọọ ja ọga ẹ lole n’Ifọ Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta

Ọmọkunrin ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn kan, Peter Okenu, pẹlu awọn mẹrin mi-in to ran pe ki wọn lọọ ja ọga to n ba taja lole, ni ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ bayii, wọn si ti fi wọn pamọ si ahamọ lẹka itọpinpin.

Stephen Anyi ni ọga Peter, oun lo lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Ifọ lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kejila, ọdun 2020, pe awọn ikọ adigunjale ẹlẹni meje kan waa ka oun atawọn ẹbi oun mọle laago meji oru ọjọ naa.

O ni pẹlu ibọn, ada ati aake lawọn ole naa de ile oun to wa ni Kajola ‘Phase 2, lagbegbe Ifọ.

O fi kun un pe niṣe ni wọn ko awọn ni papamọra, ti wọn gba ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira (150,000) lọwọ oun.

Stephen sọ pe awọn adigunjale naa gbe ẹrọ kọmputa oun lọ, o ni wọn ko awọn foonu, tẹlifiṣan ara ogiri ati mọto Toyota Highlander oun ti nọmba ẹ jẹ KJA 38 FZ, lọ.

Bayii lawọn ọlọpaa bẹrẹ si i wa awọn ole yii,

Muṣin, nipinlẹ Eko, ni ọwọ wọn si ti ba awọn mẹrin kan laipẹ yii, nigba ti wọn fẹẹ ta mọto Highlander Ọgbẹni Stephen.

Awọn mẹrin tọwọ ọlọpaa ba naa ni: Ibrahim Arowolo; ẹni ọdun mẹrinlelogun, Ṣowẹmimọ Faruk; ẹni ọdun mejidinlogun, Yusuf Azeez; ẹni ọdun mẹtalelogun ati Yakubu Ibrahim; ẹni ọdun mọkanlelọgbọn.

Awọn wọnyi ni wọn jẹwọ fawọn ọlọpaa pe awọn ko deede lọọ ja Ọ̀gbẹ́ni Stephen lole, wọn ni ọmọọṣẹ rẹ to n ba a taja ni ṣọọbu, Peter Okenu, lo bẹ awọn niṣẹ yii, oun naa lo si fun àwọn ni adirẹẹsi tawọnfi dele naa.

Bi wọn ṣe jẹwọ lawọn ọlọpaa lọọ mu Peter, oun naa si jẹwọ pe oun loun ran awọn adigunjale sọgaa oun.

DSP Abimbọla Oyeyẹmi fidi ẹ mulẹ pe mọto Highlander ti wọn fẹẹ ta, ibọn ilewọ ibilẹ ̣kan, ibọn ilewọ olojumeji to jẹ ti ibilẹ, ada mẹta ati foonu oriṣii D mẹrin lawọn gba pada lọwọ awọn tọwọ ba yii.

Awọn ọlọpaa n wa awọn yooku ninu ikọ adigunjale yii, wọn yoo si wa wọn ri gẹgẹ bi aṣẹ CP Edward Ajogun.

 

Leave a Reply