Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
O jọ pe adura ti awọn ara Ṣagamu ati ipinlẹ Ogun lapapọ ti gba lati ri ibi ti wọn tọju ounjẹ korona si nipinlẹ naa ti gba bayii pẹlu bi wọn ṣe bayii, pẹlu bi wọn ṣe ti ṣawari ibi ti ijọba tọju ounjẹ iranwọ asiko Korona si nibẹ naa, ti wọn si ti n ko kinni ọhun kẹtikẹti.
Koda, ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni awọn ti a fọrọ wa lẹnu wo ni Ṣagamu ṣi n sọ pe awọn n wa ile ounjẹ ọfẹ yii o, ti wọn ni ko sohun to ni kipinlẹ Ogun naa ma ni ipin ninu ẹ, nitori awọn ti gbọ pe gbogbo ilu pata ni wọn pin ounjẹ ọhun fun.
Afi bo ṣe di aarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹwaa yii, ti wọn ṣawari ẹ ni Ṣagamu.
ALAROYE gbọ pe ibudo awọn agunbanirọ to wa ni Ṣagamu gan-an ni awọn ounjẹ naa wa. Wọn ni ninu gbọngan tawọn ọmọ naa maa n lo ni wọn ko awọn ohun jijẹ onipaali atawọn tinu apo naa si.
Ẹnikan to n gbe nitosi ibẹ ṣalaye pe oru oni ni wọn ti kọkọ ṣi ibudo naa, awọn eeyan ko tete mọ. Ṣugbọn nigba ti yoo fi di ọwọ aarọ mọ ọsan, gbogbo ilu ti gbọ tan, ni wọn ba n ko ounjẹ lọ ni rabajigan.
Koda, awọn ṣọja to wa nibẹ ko di wọn lọwọ, wọn fi awọn eeyan naa silẹ ki wọn maa ko o ni.
ALAROYE gbọ pe awọn kan lo wa nidii ṣiṣi ti wọn ṣilẹkun ile ounjẹ yii kalẹ, ki i ṣe pe wọn ja ilẹkun wọle rara.
Bo si tilẹ jẹ pe wọn ti ti i pada lasiko ti a n kọ iroyin yii lọwọ, a gbọ pe wọn yoo tun ṣi i fun wọn to ba dọwọ alẹ mọ oru ọla.