Wọn ti ri oku ọmọbinrin ti dẹrẹba BRT gbe sa lọ ti wọn n wa

Jọkẹ Amọri

Epe nla nla ni awọn eeyan ti wọn gbọ pe ọmọbinrin to n ṣiṣẹ aranṣọ ti wọn n wa lati ọsẹ diẹ sẹyin, Ayanwọle Oluwabamiṣe, ti jade laye.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ, oku ọmọbinrin naa ni wọn ri, ti wọn si ti gbe e lọ si ile igbokuu-pamọ si  bayii, nibi ti wọn ti n ki awọn ẹbi rẹ waa wo o.

Ọkunrin kan to pe ara rẹ ni akinfikẹmi to gbe ọrọ naa sori ikanni abẹyẹfo rẹ, (twitter)  ni oun ti ba ẹgbọn ọmọbinrin naa kan sọrọ. O sọ pe ‘‘Ẹgbọn Bamiṣe wa si agọ ọlọpaa Ebute Ero lati fidi rẹ mulẹ boya Bamiṣe ni ẹni ti wọn ri oku rẹ.

Nigba to de agọ ọlọpaa naa ni wọn fi aworan oku ọmọbinrin naa han ẹgbọn rẹ, to si sọ pe Oluwabamiṣe ni. O ti wa loju ọna bayii, o n lọ si mọṣuari lati lọọ wo oku naa.

Latigba ti iroyin yii ti jade lawọn eeyan ti n ṣepe ni kikan kikan fun awọn to ṣiṣẹ ibi naa, ti wọn si n bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa, bẹẹ ni wọn n sọ pe BRT paapaa ti lewu lati wọ bayii pẹlu iṣẹlẹ to ṣẹlẹ si ọmọ yii.

Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja yii ni ariwo gba ilu pe wọn n wa ọmọbinrin kan to wọ mọto BRT, ti wọn ko si gburoo rẹ mọ latigba naa. Dẹrẹba BRT kan lo gbe ọdọmọdebinrin ti ko ju ẹni ọdun mejilelogun lọ ọhun, Oluwabamiṣe Ayanwọla, to wọ bọọsi rẹ lọ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii.

Ilu Ajah ni ọmọbirin ti wọn lo n ṣiṣẹ awọn to n ranṣọ yii n gbe ni Chevron Estate. Ṣugbọn lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, o kuro nile to n gbe l’Ajah, o loun fẹẹ lọọ lo opin ọsẹ lọdọ ẹgbọn oun to n gbe niluu Ọta, nipinlẹ Ogun.

Nigba naa lo wọ bọọsi BRT kan ti nọmba rẹ jẹ 240257.

Nigba ti wọn n lọ ti dẹrẹba naa ko gbe ero mi-in ni gbogbo awọn ibudokọ ti wọn kan loju ọna lara bẹrẹ si i fu ọmọbinrin yii. Eyi lo mu ki ọmọbinrin yii bẹrẹ si i ba ọrẹ rẹ kan sọrọ lori foonu rẹ. O sọ fun ọrẹ rẹ yii pe ko jọwọ, ko maa gbadura foun o, pe oun fura si dẹrẹba mọto ti oun wọ yii.

Wọn ni ọrẹ rẹ yii sọ fun un pe ko bọ silẹ to ba ti de ibudokọ Oworonṣhoki ko too de ibudokọ Oshodi.

Bakan naa ni wọn ni ọmọbinrin ti wọn n wa yii fi fidio bi inu mọto naa ṣe dudu to han ọrẹ rẹ yii.

Eeyan mẹrin ni wọn lo wa ninu bọọsi BRT ọhun. Ọkunrin mẹta ati obinrin kan, ti obinrin naa si jokoo sẹyin ninu ọkọ ọhun gẹgẹ bi Oluwabamiṣe ṣe sọ fun ọrẹ rẹ, to si fi nọmba bọọsi ọhun ranṣẹ si i pẹlu pe aibaa mọ o. To si tun tẹnu mọ ọn fun ọrẹ rẹ yii pe ko maa gbadura foun.

Ohun ti wọn gbọ mọ nipa ọmọbinrin naa niyi titi di ba a ti n sọ yii gẹgẹ bi iya rẹ ṣe sọ.

Ọkan ninu awọn mọlẹbi ọmọbinrin naa ni awọn lọ sọdọ ọga agba awọn onimọto BRT, awọn si ba ọga yii atawọn mẹta mi-in ti wọn sọ fawọn pe bi awọn ṣe gbe ọrọ naa lọ sori ẹrọ ayelujara le ṣe akoba fun iwadii awọn ọlọpaa lori rẹ.

Bakan naa ni wọn sọ pe awọn gan-an kọ ni awọn n gba oṣiṣẹ, ati pe awọn ti fi to ẹni to n ba wọn gba oṣiṣẹ leti. Bẹẹ ni wọn sọ pe ẹni to ṣe oniduuro fun dẹrẹba naa ti sa lọ. Wọn ko ti i ri.

Alukoro ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Adekunle Ajiṣebutu, fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ, bẹẹ lo ni iwadii ti n lọ lori rẹ.

Bakan naa ni ọga ọlọpaa Eko, Abiọdun Alabi, ni gbogbo ohun to ba gba lawọn yoo fun un lati ri i pe ọmọ naa di riri.

Ṣugbọn o jẹ ohun ibanujẹ pe bo tilẹ jẹ pe wọn ri ọmọ naa, oku rẹ ni wọn pada ri.

Bakan naa la gbọ pe wọn ti ri awọn meji mu lori ọrọ Oluwabamiṣe yii. Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Adekunle Ajiṣebutu fidi eleyii mulẹ, bẹẹ lo sọ pe ki ẹjọ naa ma baa falẹ rara ni Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Abiọdun Alabi fi pasẹ pe ki wọn tete taari rẹ si ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ fun iwadii siwaju si i.

Bẹẹ lo ni awọn meji tọwọ tẹ naa n ran awọn lọwọ lori iwadii awọn.

 

 

Leave a Reply