Ọlawale Ajao, Ibadan
Wọn ti sinku Asẹyin tilẹ Iṣẹyin, Ọba Abdul Ganiyu, Adekunle Salawudeen (Ajinẹsẹ Kin-in-ni), to waja lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.
Lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keje, ọdun 2022, lọba nla to jẹ igbakeji alaga igbimọ awọn lọbalọba ipinlẹ Ọyọ dakẹ sileewosan University College Hospital, UCH, n’Ibadan.
O to bii oṣu meloo kan ti ojojo ti n ṣogun Ọba Adekunle, lati bii ọsẹ meji ni wọn ti da a duro si UCH, kọlọjọ too de ba a nibẹ lọsan-an ọjọ Aiku.
Ipapoda ori ade yii lẹlẹẹkeje ọba ti yoo waja nipinlẹ Ọyọ laarin oṣu mẹjọ sasiko yii.
Awọn ọba to ti kọkọ waja laarin asiko naa ni Ajoriwin tilu Igbẹti, Ṣọun ti Ogbomọṣọ, Olubadan tilẹ Ibadan, Aṣigangan ti Igangan, Alaafin Ọyọ ati Onijẹru ti Ijẹru, bo tilẹ jẹ pe wọn ti fi Olubadan tuntun jẹ ni nnkan bii oṣu mẹrin sẹyin.
Lọjọ Kẹwaa, oṣu Keji, ọdun 2022 yii, niroyin ti kọkọ gba ilu kan pe Ọba Adekunle ti waja, ṣugbọn ti ọrọ ko pada ri bẹẹ mọ, ko too di pe iku pada ka a mọ ori apere, to si ṣe bẹẹ jẹ ipe awọn baba nla ẹ.
Lọsan-an ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2022 yii, ni wọn sinku Kabiesi sibi ti awọn baba nla ẹ sun si lagbegbe kan ti wọn n pe ni Itan, lọna Isalu, niluu Iṣẹyin.
Ẹni ọdun mejilelọgọta (62) lọba naa ko too dara pọ mọ awọn baba nla ẹ lẹyin ọdun mẹẹẹdogun (15) to lo lori itẹ.
Ninu ọrọ ibanikẹdun ti Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, fi ranṣẹ si idile Asẹyin ati gbogbo ọmọ ilu naa lapapọ, gomina sọ pe ipapoda ọba naa ba oun lojiji, o si ba oun ninu jẹ gidigidi.
Makinde, ẹni ti Ọgbẹni Taiwo Adisa ti i ṣe Akọweeroyin rẹ sọrọ naa lorukọ rẹ, ṣapejuwe ori ade ọhun gẹgẹ bii ẹni ti idagbasoke ipinlẹ Ọyọ jẹ logun nigba aye ẹ.
Ọgọọrọ leekan leekan ilu lo ti fi ibanujẹ ọkan wọn han nipa bi dokita to jọba Asẹyin yii ṣe papoda.
Diẹ lara wọn ni Sẹnetọ Teslim Fọlarin, to jẹ oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ọyọ labẹ ẹgbẹ oṣelu APC; oludije fun ipo gomina lorukọ ẹgbẹ oṣelu Accord Party, Oloye Adegoke Adelabu; pẹlu Sẹnetọ Kọla Balogun, ẹni to n ṣoju ẹkun idibo Aarin Gbungbun ipinlẹ Ọyọ nileegbimọ aṣofin apapọ niluu Abuja.