Faith Adebọla
Hajiya Hadiza Shagari, iyawo aarẹ ilẹ wa tẹlẹri, Oloogbe Alaaji Shehu Shagari, ti dagbere faye, wọn si ti sinku rẹ sitẹkuu ijọba apapọ, niluu Abuja.
Gẹgẹ bi atẹjade kan ti ọmọọmọ aarẹ ana naa fi lede lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee yii, Alaaji Bello Bala Shagari ni:
“O ṣe wa laaanu lati kede iku mama wa olufẹ, Hajiya Hadiza Shehu Shagari, ti i ṣe iyawo Oloogbe Aarẹ Shehu Usman Aliyu Shagari, GCFR (Turakin Sokoto).
A padanu wọn ni aarọ oni, ọjọ kejila, oṣu kẹjọ, ọdun 2021, lẹyin ti wọn ti lugbadi arun Korona, ti wọn si ti n gba itọju lori aisan ọhun fungba diẹ ni ibudo iyasọtọ Gwagwalada Isolation Centre, niluu Abuja.
Ẹni ọgọrin ọdun (80) ni Hajiya Hadiza Shagari.”
Ba a ṣe gbọ, adura akanṣe fun oku oloogbe naa waye ni mọṣalaṣi apapọ ilẹ wa, l’Abuja.
Ọpọ ọmọ ati ọmọọmọ lo gbẹyin oloogbe naa.